Ọlọpaa fofin de yinyin banga lakooko ọdun Keresi nipinlẹ Ogun

Adewale Adeoye

K’ekun ile gbọ ko sọ fun t’oko, ki adan gbọ, ko ro foobẹ, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun f’ọrọ naa ṣe pẹlu bi wọn ṣe n laago ikilọ fun gbogbo awọn olugbe ipinlẹ naa pe awọn ti fofin de yiyin banga, ohun iṣere alariwo to maa n bu gbamu bíi ibọn lasiko ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun níbikíbi nipinlẹ naa.

Wọn ni ọpọ araalu ni ko fi bẹẹ mọ iyatọ to wa laarin iro banga ọhun ati iro ibọn, ati pe ipaya ati ibẹrubojo ni ariwo kínní náà maa n da sọkan awọn olugbe adugbo gbogbo kaakiri ilu nipinlẹ naa.

ALAROYE gbọ pe awọn olugbe ilu bii: Ṣagamu, Ijẹbu-Ode, Ikẹnnẹ ati Sango-Ota, ni wọn pariwo, ‘ẹ gba wa’ lọ sileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa pe ipaya ibẹru ati wahala nla ni banga tawọn kan maa n yin ọhun n da sara awọn araalu ti wọn fi gbe igbesẹ ọhun pe, ẹnikẹni ko gbọdọ yin ohun iṣere ọhun laarin ilu mọ, paapaa ju lọ, lọdun yii to jẹ pe awọn ọmọ jaguda pọ nita gidi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi ọrọ ọhun mulẹ fawọn oniroyin ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa ni Eleweran, l’Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun yii, sọ pe ọpọ awọn araalu ta a darukọ soke ọhun ni ipaya yiyin banga ọhun ko jẹ ki wọn sun dọkan mọ rara, nitori pe wọn ko mọ iyatọ to wa laarin iro banga ati ti ibọn tawọn janduku fi waa n ṣọṣẹ laarin ilu.

Fun idi eyi, alukoro ni o ti deewọ fawọn araalu bayii lati yin banga lakooko yii. O ni awọn ko ni i foju to daa wo ẹni to ba kọ eti ikun si ikilọ naa.

Leave a Reply