Eedi ree o, ọkunrin yii fipa ba ọmọọdun meji laṣepọ, o lọti toun mu yo lo fa a

Faith Adebọla

Bawọn kan ṣe n rọjo eebu ati epe rabandẹ rabandẹ le afurasi ọdaran yii, Buguwa Kwaji lori, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ọrọ kati-kati lo n sọ lẹnu, awọn o gbọdọ gbọ ọ mọ. Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun naa ni pe o ki ọmọ pinniṣin, ọmọọdun meji pere mọlẹ, o si yọ nnkan ọmọkunrin abẹ ẹ ti ọmọ yii, o fipa ba a sun pẹlu inira. Nigba tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, o jẹwọ pe loootọ loun huwa buruku yii, ṣugbọn ki i ṣe ẹbi oun naa, ọti buruku kan toun mu lọjọ yii lo fa a, o lọti yii lo gbodi lara oun toun fi dan palapala wo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, SP Suleiman Yahaya Nguroje, sọ lasiko to n fidi ọrọ yii mulẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla yii, pe olobo kan lo ta awọn lori iwa ọdaran ti Buguwa hu, lawọn fi dọdẹ rẹ, tawọn si mu un lọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun yii. Atigba naa lo si ti wa lahaamọ awọn, nibi tawọn ti n ba iwadii ijinlẹ lọ labẹnu nipa rẹ.

Wọn ni abule kan ti wọn n pe ni Aljannaru, nijọba ibilẹ Song, nipinlẹ Adamawa, lafurasi ọdaran yii n gbe, ibẹ naa lo si ti huwa arufin yii.

Nigba tawọn ọlọpaa fi pampẹ ofin gbe e de akolo wọn, ti wọn si bi i leere ọrọ, wọn lafurasi naa ṣalaye pe:

“Loootọ ni, ẹ fori ji mi. Ọti lile kan ti wọn n pe ni Voltage ni mo mu yo lọjọ yẹn, ibi tọti naa pa mi si ni mo si rọra dubulẹ si jẹẹ, mi o mọgba ti ọmọdebinrin yii de ọdọ mi, to bẹrẹ si i ba mi ṣere, o fọwọ pa mi lara, niṣe lara mi dide wan-an, mi o si le kọntiroolu ara mi mọ. Mo ba a laṣepọ loootọ, tori ara mi ti dide gidi fun ibalopọ gidi ni.”

Alukoro fi kun alaye rẹ pe ẹgbọn ọmọdebinrin ti Buguwa ṣe yankan-yankan yii lo ka a mọ’bi to ti n huwa aidaa ọhun, niyẹn ba figbe ta. Ki awọn araadugbo si too wọle lati wo ohun to n ṣẹlẹ, jagunlabi ti wọn ṣokoto rẹ, o ti sa lọ, amọ wọn le e mu, wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ.

Ni bayii, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Afọlabi Babalọla, ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ tete pari iwadii wọn, ki wọn le bẹrẹ igbesẹ lati wọ ọkunrin naa lọọ siwaju adajọ. Wọn ni to ba de ọhun ni yoo too mọ itumọ ohun to ṣe yii daadaa labẹ ofin.

Leave a Reply