Lori oku MohBad, oṣere yii sọko ọrọ sawọn  ọlọpaa Naijiria

Faith Adebọla

Afaimọ ni ki i ṣe owe, “iwọn ni nnkan dun mọ” ni gbajugbaja oṣere tiata ati onkọrin ilẹ wa kan, Tonto Dikeh, n pa fawọn ọlọpaa bayii, pẹlu bi arẹwa obinrin to saaba maa n ṣere oyinbo naa ṣe fibinu gba oju opo ayelujara rẹ lọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla yii, to si sọko ọrọ sawọn ọlọpaa ilẹ wa lori bi wọn ṣe n fi ọrọ iwadii iku gbajumọ olorin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan tun mọ si Mohbad falẹ, o ni ki wọn yọnda oku ẹ fawọn lati le lọọ sin in ni sinsin ẹyẹ to tọ si i.

Obinrin ọmọ bibi ipinlẹ Rivers, to tun mu oṣelu mọ ere ati orin yii, sọ pe o ya oun lẹnu pe pẹlu bi oun ṣe gbara-ta lori iku Mohbad, tawọn si reti pe ki awọn agbofinro ṣewadii wọn lai sọsẹ, ki idajọ ododo si waye, niṣe lọrọ iwadii iku ọdọmọde olorin naa tun wa n fa bii igbin, ti ko si ti i si koko kan pato teeyan le ri di mu.

Ninu ọrọ ti Tonto Dikeh, ẹni ọdun mejidinlogoji, kọ lati fi ẹdun ọkan rẹ han siṣẹlẹ yii, o ni:
“Ẹ gbe oku Mohbad jade fun wa ka le sin in tiyi-tẹyẹ o. Ọrọ iwadii iku rẹ tẹ ẹ fọwọ yọbọkẹ mu, tẹ ẹ si tun n foni-in doni-in, fọla dọla, lori ẹ yii ti su-u-yan. T’ẹnikẹni o ba le sọrọ, emi aa sọrọ ni temi o.

“Mo mọ bi iṣẹlẹ yii ṣe ka mi lara to, ti mo lo akoko ati okun mi, to si wu mi pe ki idajọ ododo waye. Bi wọn ṣe n sọ, wọn ni ka fun ọlọpaa laaye ati asiko lati ṣe iṣẹ wọn.

“Ni tododo, a ti fun awọn ọlọpaa laaye to pọ ju ohun ti wọn nilo lọ. Iru ọrọ yii kọ lo yẹ ka daṣọ bo lori mọlẹ. Idajọ ododo la fẹ!” Bẹẹ lo kọ ọrọ ọhun, to si fi orukọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin, sabẹ rẹ lati fihan pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko loun n dari ọrọ oun si.

Ọgọọrọ awọn to sọrọ lori ohun ti Tonko Dikeh wi yii ni wọn kin obinrin naa lẹyin, tawọn mi-in si bẹnu atẹ lu awọn ọlọpaa lori ọrọ iku Mohbad.

Ademachismo ni, “ohun to fa a ti esi ayẹwo iṣegun ti wọn ṣe fun Mohbad ko fi ti i jade dasiko yii, ẹ gbagbe ẹ, wọn ti sẹtu ara wọn ni.”

Princeniky27 ni, “amọ eyi ba-a-yan lọkan jẹ gidi o. Wọn maa huwa irẹjẹ to ba dasiko ibo, wọn tun rẹ oku jẹ pẹlu, iru orileede raurau la n pe ni Naijiria yii gan-an na?”

Ni ti Blacross, oun ni: “Ẹ lọọ hu oku ẹ jade, ẹ f’ọbẹ la a, amọ ẹ o fun wa lesi ayẹwo. Ẹ jọọ, ẹ yọnda oku ololufẹ wa fun wa ka lọọ sin in, tori bo ṣe wu yin lẹ n ṣe oku ẹ bayii o”.

Kingdeewhy6371 sọ pe: “Ẹni to kun ọrẹbinrin ẹ bii ẹran, to waa ko ageku oku rẹ sinu apo, wọn ti ṣayẹwo si oku naa, esi si ti jade tipẹ, amọ iku Mohbad to waye ṣaaju tiẹ ko ti i lesi, ṣe awọn oniṣegun to ṣayẹwo naa ni wọn tun ṣe iyẹn ni.”

Bayii ni koowa wọn fi ero rẹ han.

Leave a Reply