Awọn eleyii fẹẹ sa kuro ni Naijiria tipatipa, ẹ wo bi wọn ṣe fẹmi ara wọn wewu

Monisọla Saka

Afurasi ẹni ọdun mejidinlogun kan, Michael Daniel, atawọn mẹta mi-in tọwọ tẹ lasiko ti wọn fẹẹ ba inu ile ẹru ọkọ oju omi sa lọ soke okun ti jẹwọ pe nitori ebi, iṣẹ ati iya to n ba awọn finra lorilẹ-ede yii lawọn ṣe fẹẹ sa lọ.

Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ọwọ ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi ilẹ wa, Nigerian Navy, tẹ wọn lasiko ti wọn lọọ ha ara wọn mọ’nu ile ẹru ọkọ oju omi nla to n lọ siluu Dubai, lorilẹ-ede United Arab Emirates.

Lasiko tawọn ọmọ ogun n ṣe paturoolu ni wọn ri awọn mẹrẹẹrin naa nibi ti wọn ha ara wọn mọ si pẹlu ounjẹ ipapanu ti wọn di sinu lailọọnu.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ wọn, H. A Collins, fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, nibẹ lo ti ṣalaye pe ọga agba awọn ikọ NNS Beecroft, Commodore Kọlawọle Oguntuga, sọ pe awọn kan lo ta wọn lolobo ti ọwọ awọn fi tẹ awọn eeyan mẹrẹẹrin naa.

O tẹsiwaju pe bi wọn ṣe debẹ ni wọn gbọ kurukẹrẹ irin ẹsẹ eeyan nibi ti wọn maa n kẹru si, bi wọn si ṣe wọ inu ibẹ lọ ni wọn ba awọn atilaawi pẹlu ijẹkujẹ ati omi inu ọra ti wọn di sinu polibaagi lorigun kan.

Awọn mẹrẹẹrin ti ọwọ tẹ yii ni Michael Daniel, ẹni ọdun mejidinlogun (18), lati ipinlẹ Ondo, Ebi Agrive, ẹni ọdun mejilelogun (22), lati ipinlẹ Bayelsa, Lucky Amusu, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), lati ipinlẹ Eko, ati Goodness Edu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), to wa lati ipinlẹ Akwa Ibom.

Ọga agba awọn ikọ yii ni yatọ si pe awọn eeyan wọnyi n fi ara wọn sipo to lewu pupọ fun ẹmi wọn pẹlu irinajo tun-un-nu tun-un-nu ori omi yẹn, agaga pẹlu inu kọlọfin ti wọn lọọ ha ara wọn mọ, o ni ewu ni wọn tun jẹ fun ọkọ oju omi yẹn ati gbogbo ero inu ẹ, to si le ṣe bẹẹ di ọran nla si ọrun orilẹ-ede yii.

O sọrọ siwaju si i pe awọn ti fa awọn mẹrẹẹrin naa le ileeṣẹ to n ri si iwọle ati ijade awọn eeyan lorilẹ-ede yii, Nigerian Immigration Service (NIS) lọwọ, fun igbesẹ to ba yẹ ni gbigbe.

Leave a Reply