Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbogbo awọn adajọ, awọn amofin, awọn agbofinro atawọn araalu ti wọn ni ohun kan tabi omi-in lati ṣe ninu ọgba ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Oṣogbo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn ko lanfaani lati wọle.
Agbarijọ awọn oṣiṣẹ kootu naa ni wọn tu yaaya jade lati fẹhonu han si ohun ti wọn pe ni iwa fa-mi-lete-n-tutọ ti adajọ agba l’Ọṣun, Onidaajọ Adepele Ojo n hu si wọn.
Oniruuru akọle ni wọn gbe lọwọ, ti wọn si n kọrin lọ sokesodo pe awọn ko gbe igbe aye ẹru mọ labẹ isakoso Adepele.
Alaga wọn, Ọgbẹni Gbenga Eludire, ṣalaye pe gbogbo ọna lawọn ti gba lati jẹ ki adajọ agba ri inira ti awọn n la kọja, sibẹ, iwa ko-kan-mi lobinrin naa n hu.
Eludire ṣalaye pe lọdun mẹta sẹyin ni Adepele sọ pe ki awọn oṣiṣẹ kan lọọ rọọkun nile lai gbọ awijare lẹnu wọn, o ni ile-ẹjọ tun da awọn kan lare lara wọn, sibẹ, obinrin yii ko gba wọn pada sẹnu iṣẹ.
O fi kun alaye rẹ pe awọn kan ti ku lara awọn ti Adepele da duro lai nidii yii, nitori ko si abuja kankan lọrun ọpẹ fun wọn ju owo-oṣu ti wọn n gba yii lọ.
O ṣalaye pe lati ọdun 2016 ni ko ti fun ẹnikẹni laaye lara awọn oṣiṣẹ kootu lati lọ fun ifimọ-kunmọ lẹnu iṣẹ wọn, eleyii ti ko ri bẹẹ tẹlẹ.
O ni ọdọọdun nijọba maa n san owo ajẹmọnu fun aṣọ rira, iyẹn (wardrobe allowance) sinu aṣunwọn kootu, sibẹ Adepele ko fun awọn oṣiṣẹ lowo yii lati ọdun 2021.
Eludire tẹ siwaju pe awọn ko ni i sinmi ariwo yii titi ti Onidaajọ Adepele Ojo yoo fi fun awọn ni gbogbo ẹtọ to tọ si awọn.