Nitori awọn ọrẹ ọmọ ẹ ti wọn lawọn fẹẹ sinku ẹ, Baba Mohbad fabinu yọ

Adewale Adeoye

Ni idahun sọrọ to n lọ lori ẹrọ ayelujara, leyii tawọn ọrẹ Ọladimeji Alọba, Mohbad, otoun naa jẹ olorin hipọọpu, Bella Shurmda, sọ pe o ti yẹ kawọn ọlọpaa jọwọ oku Oloogbe Mohbad silẹ fawọn ẹbi ati ọrẹ rẹ ki wọn le ṣeto isinku oloogbe naa lona to bojumu. Alagba Joseph Alọba ti i ṣe baba Mohbad ti yari kanlẹ, o si fajuro gidi si bi wọn ṣe ni ki wọn waa sin oku ọmọ naa. Baba yii ni ko sẹni to gbọdọ lọọ gba oku ọmọ oun lati ṣeto isinku kankan gẹgẹ bawọn kan ṣe n gbero rẹ bayii. O ni o digba t’oun ba ri idajọ ododo gba lori iku ọmọ oun loun maa too sin in, ati pe awọn gbọdọ mu diẹ lara ẹya ara oloogbe naa lati fi ṣayẹwo ejẹ si ọmọ kan ṣoṣo ti wọn sọ pe o fi silẹ saye lọ, kawọn le mọ boya loootọ, ọmọ oun lo ni ọmọ naa tabi bẹẹ kọ.

Oṣerebirin onitiata ilẹ wa kan, Tonto Dike lo kọkọ gbe e sori ẹrọ ayelujara pe o ti yẹ kawọn ṣeto isinku to bojumu fun oloogbe naa, ati pe lẹyin tawọn ba ṣeto isinku ọhun tan lawọn maa too mọ igbesẹ to ku lori ọmọ ti oloogbe fi silẹ saye. Ko pẹ sasiko ti oṣere naa sọrọ yii tan ti Bella Shurmda to jẹ ọkan pataki lara  kori-kosun oloogbe naa tun fi bọ sita, to si rọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko pe ki wọn yọnda oku Mohbad fawọn ẹbi ati ọrẹ, kawọn le ṣeto isinku rẹ, ko le lọọ sinmi jẹẹ lọdọ ẹlẹdaa rẹ.

Baba oloogbe naa sọ ninu fidio kan to ṣe sita lori ọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, pe, ‘‘Ko sẹni to gbọdọ gbiyanju lati lọọ tẹwọ gba oku ọmọ mi lati ṣeto isinku kankan fun un lai jẹ pe mo paṣẹ tabi mo fọwọ siru igbesẹ bẹẹ. Ohun ti mo n sọ gan-an ni pe o ni diẹ lara ẹya ara oloogbe ta a gbọdọ mu lọ fun ayẹwo ẹjẹ lati fidi ootọ mulẹ boya ojulowo ọmọ ni wọn n gbe kaakiri pe ọmọ oloogbe ni tabi ki i ṣe bẹẹ. Oriṣiiriṣii ahesọ ni mo ti n gbọ nigboro pe awọn kan n kora wọn jọ lati gbokuu ọmọ mi, ki wọn si sin in lai jẹ pe mo mọ si i, ko sẹni to gbọdọ san aṣọ bẹẹ ṣoro o, ko sohun kankan tẹ ẹ fẹẹ ṣe lori oloogbe to gbọdọ ṣokunkun si mi, niwọn igba ti mo ṣi wa laye. O di dandan ka ṣe ayẹwo ẹjẹ f’ọmọ oloogbe’’.

Bẹẹ o ba gbagbe, Oloogbe Mohbad ku lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn,  ti awọn ẹbi rẹ si tete sinku rẹ lọjọ keji siluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, ṣugbọn nigba ti ariwo awọn ololufẹ oloogbe naa pọ gidi, ti wọn si n sọ pe eru wa ninu iku to pa a lo mu kawọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii nipa rẹ, ti wọn si lọọ hu oku rẹ jade nibi ti wọn sin in si.

O ti le loṣu meji sẹyin bayii ti wọn ti ṣayẹwo sokuu oloogbe naa, ṣugbọn ti wọn ko ti i gbe esi ayẹwo naa jade sita fẹnikẹni.

Leave a Reply