Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, ni ọwọ awọn tẹ afurasi kan lara awọn to ṣeku pa akẹkọọ ileewe gbogbonise tijọba apapọ to wa niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, (Federal Polytechnic Ọffa), Omidan Toyin Bamidele, tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣa pa mọ’nu ile ẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ajayi Ọkasanmi, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti ni Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbọ si iṣẹlẹ to gba omije loju ẹni to waye lagbegbe Dapson, niluu Ọffa, nibi ti wọn ti da ẹmi akẹkọọ Ọffa Poli kan, Toyin Bamidele, legbodo. Ajayi ni ni kete tileeṣẹ ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ naa ni wọn lọ si agbegbe ọhun, tawọn si ba oku ọmọbinrin arẹwa yii ninu agbara ẹjẹ. Wọn gbe e lọ sileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Wale Clinic and Hospital, nibi ti wọn ti fidi ẹ mulẹ pe Toyin ti ku patapata, ti wọn si ti gbe oku ẹ lọ si yara igbooku-si bayii fun ayẹwo to peye.
O tẹsiwaju pe lẹyin iwadii ijinlẹ lọwọ tẹ afurasi kan lara awọn to pa ọmọbinrin naa, to si n ran awọn ọlọpaa lọwọ lati ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii iṣẹlẹ naa.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Ọlaiya, rọ gbogbo olugbe ipinlẹ ọhun lati wa ni oju lalakan fi n ṣọri lasiko yii, nitori pe awọn eeyan buruku ti pọ lawujọ.
O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i kaaarẹ lati maa daabo bo ẹmi ati dukia gbogbo olugbe ipinlẹ naa.