Awọn eeyan bara jẹ gidigidi nibi isinku olukọ fasiti ti ọmọọdọ rẹ gun pa

Adewale Adeoye

Beeyan ba jẹ ori ahun, to jẹ pe onitọhun daju ju nnkan mi-in lọ, bo ba wa nibi ti ẹbi, ọmọ, ara, ọrẹ ati ojulumọ ti ṣeto isinku Oloogbe Dokita Funmilọla Adefọlalu, olukọ agba ileewe ‘Federal University Of Technology’ (FUT), to wa niluu Minna, nipinlẹ Niger, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ko si ki tọhun ma bomi loju nitori awọn ọrọ aro to n jade lẹnu awọn ọmọ atawọn mọlẹbi oloogbe naa, to fi mọ awọn ọmọ ijọ to n lọ.

Poroporo lomi n ja bọ loju awọn to wa nibi isinku naa. Koda, awọn kọọkan ninu awọn alabaaṣiṣẹpọ rẹ nileewe, atawọn ọmọ ijọ ti wọn ti kọkọ n ṣe ọkan akin, ti wọn n mu ibanujẹ naa mọra, pada bara jẹ nigba ti awọn ọmọ oloogbe naa bẹrẹ si i sọrọ aro nipa iya wọn yii.

Ohun to mu ki ọrọ ọhun buru ni pe awọn ọmọ yii ko ni baba mọ laye, ọkọ oloogbe naa ti ku, iya wọn to ku ti wọn tun n wo loju lawọn ọmọ buruku naa tun pa nipa ika. Ọrọ naa si dun wọn de pinpin ọkan bi wọn ṣe n daro rẹ tẹkun-tomije.

ALAROYE gbọ pe ilana ẹsin Onigbagbọ ni wọn fi ṣe isin fun obinrin yii ninu ijọ to n lọ nigba aye ẹ, iyẹn Mercy Ministry.

Nibi ẹyẹ ikẹyin ọhun ni Omidan Toluwalọpẹ Adefọlalu-Odogiyon, ti i ṣe akọbi oloogbe lobinrin ti sọ pe, ‘‘O ma ṣe o, igba gbogbo niyaa mi maa n fun mi niṣẹ ṣe bii igba to jẹ pe a ko tun ni i foju kan ara wa mọ rara, mama mi tootọ, ọkan mi gbọgbẹ gidi nigba ti mo gbọroyin iku yin, Mi o mọ pe ọkan eeyan le kun fun ironu ati ibanujẹ bayii, ki tọhun si tun maa mi. O ṣoro fun mi lati gbagbọ gidigidi. Mo ni ọpọlọpọ ibeere lọkan mi lati beere, ṣugbọn ko si ohunkohun to mura ọkan mi silẹ fun ibanujẹ, ikerora ọkan, ijẹrora, imi ẹdun ati ọgbẹ ọkan ti iku yin mu ba mi.

‘‘Mama mi gbe igbe aye to daa nigba to fi wa loke eepẹ, ki i baayan binu, bẹẹ ni oorun ki i wọ ba ibinu lọkan rẹ, mi o ki i ṣe aṣẹda to da yin saye, ṣugbọn ohun ti mo mọ daadaa ni pe o gbe igbe aye to ni ifarajin. Mo si mọ pe ẹ o ti maa jẹgbadun isinmi ti ẹ maa n sọrọ nipa rẹ. Pe ọkan mi yoo maa ṣafẹri yin nigba gbogbo yoo da bii asọdun. Oriṣiiriṣii iranti la ni nipa ara wa, eyi to si dun mi ju lọ ni awọn ipinnu ati eto loriṣiiriṣii ta a ni lọkan, ta a ni fun ọjọ iwaju lati jọ mu ṣẹ.

‘‘Mo ti n ṣafẹẹri awọn ọrọ ta a maa n ba ara wa sọ, bẹ ẹ ṣe maa n rẹrin-in, adura tẹ ẹ maa n gba fun mi ati bẹ ẹ ṣe maa n fi oriṣiiriṣii nnkan kẹ mi. Ẹ wa nibẹ fun mi lasiko awọn igbokegbodo mi nile aye, ati lasiko awọn idojukọ mi. Pe mo n ṣaferi yin bayii jẹ ohun to wuwo lọkan mi. Ṣugbọn mo dupẹ pe mo ni iru yin ni iya fun iwọnba akoko ti mo fi ni yin, mo si dupẹ fun iranti rere ti mo n ni nipa yin’’ Bayii ni Fumilọla pari ọtọ rẹ tẹkun-tomije. Bo si ti n ka a lawọn eeyan n ṣomi loju, ti wọn n mi imi ẹdun.

Bakan naa tun ni ẹkun tun n pe ẹkun ran niṣẹ nigba ti Ṣeyi Adefọlalu, ti i ṣe ọmọkunrin oloogbe naa to ka itan igbesi aye mama rẹ sọ pe, ‘Mama mi ọwọn, bii ala lo ṣi n jọ loju mi pe mi o ni i ri yin mọ bayii, mi o ro pe iku le pa yin ki ọdun yii too pari rara, ṣugbọn bo ṣe wu Oluwa lo n ṣọla rẹ. Baba mi ko si laye mọ lati mọ iru ọkunrin ti mo dagba lati jẹ bayii. Ẹyin naa to yẹ kẹ ẹ wa laye lati mọ iru baba ti ma a jẹ fawọn ọmọ ti ma a bi tun ti lọ bayii, ta waa leni naa ti ma a lọọ mu iyawo ti mo fẹẹ fẹ lọọ ba, ta lẹni naa ta a wa lẹgbẹẹ mi ti ma a maa ke si lọrun bi mo ba di baale ile tan. Laipẹ yii lemi pẹlu yin jọ ṣawada nipa obinrin ti ma a fi ṣaya nile aye mi, ṣugbọn ẹ ko si mọ bayii lati mọ iru obinrin bẹẹ, eyi ko daa to rara, to si ba ọkan mi jẹ gidigidi.

‘‘Bawo ni mo ṣe fẹẹ gbagbe ohùn yin, bawo ni mo ṣe fẹẹ gbagbe bi ẹ ṣe maa n fẹnu ko mi lẹnu, bi ẹ ṣe maa n so mọ mi, bẹ ẹ ṣe maa n lu mi, bẹ ẹ ṣe maa n waasu fun mi. Bawo ni mo ṣe le gbagbe. Ọrọ da lẹnu mi, omije da loju mi. Loootọ ni ala maa n da bii pe ootọ ni, ṣugbọn eleyii ko jọ ootọ fun mi rara, mi o si ti i gbagbọ pe bi ọdun yii ṣe maa pari fun mi ree, ṣugbọn ohun gbogbo ye Ọlọrun Ọba to da gbogbo wa pata. Iya Jesu, gẹgẹ bii orukọ inagijẹ ti mo fun yin, akọni obinrin ninu ohun gbogbo, sun ree lookan aya Oluwa rẹ’’.

Ninu ẹri tirẹ, pasitọ agba ijọ ti oloogbe naa n lọ nigba aye rẹ, Ojo Peters, ni, ‘‘Ko sohun ti oloogbe ko ṣe fun Oluwa nigba aye rẹ, o fara sin in, o si sin in tọkan-tọkan ninu ohun gbogbo, bakan naa lo rọ awọn ẹbi ati ara ti wọn n bara jẹ nibi oku ọhun pe ki wọn fiye denu, o ni ohun gbogbo ye Ọlọrun ọba.

Obinrin to ku yii ni wọn ni o jẹ pasitọ ẹka ijọ kekere ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ, to si jẹolufọkansin tootọ to fẹran Ọlọrun.

Itẹkuu kan to wa lagbegbe David Mark, niluu Minna ni wọn si oloogbe naa si

Leave a Reply