Awọn agbebọn ji nọọsi gbe l’Ọṣun, miliọnu mẹwaa ni wọn n beere

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Obinrin nọọsi kan, S. Ogunyinka, la gbọ pe awọn agbebọn ti ji gbe loju ọna Iwo si Ileogbo, nipinlẹ Ọṣun, bayii.

Inu oko la gbọ pe obinrin yii ati ọkọ rẹ ti n bọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ti wọn fi ko sọwọ awọn agbebọn naa.

ALAROYE gbọ pe wọn yinbọn lu ọkọ nọọsi yii, to si jẹ pe diẹ lo ku ki ẹmi bọ lara ẹ ko too di pe wọn gbe obinrin naa lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ.

A gbọ pe ileewosan alabọọde kan, iyẹn Primary Healthcare Department, nijọba ibilẹ Ọla-Oluwa, ni Bodè-Òsì, nipinlẹ Ọṣun, lobinrin yii wa.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ẹlẹgbẹ obinrin naa ṣe sọ, wọn ni awọn agbofinro ko gbe igbesẹ to nitumọ kankan lati ọjọ Furaidee ti obinrin yii ti wa lakolo awọn ajinigbe.

O ṣalaye pe miliọnu lọna ogun Naira lawọn ajinigbe yii kọkọ n beere lọwọ awọn mọlẹbi obinrin yii gẹgẹ bii owo itusilẹ, ṣugbọn nigba ti ẹbẹ pọ ni wọn din in ku si miliọnu mẹwaa Naira.

O fi kun ọrọ rẹ pe latigba naa lawọn ti n dawo jọ lati le fi ran awọn mọlẹbi rẹ lọwọ, ko le gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti n gbe igbesẹ lati gba obinrin yii silẹ, ati lati fi panpẹ ofin mu awọn ti wọn ṣiṣẹ naa.

Leave a Reply