Eyi nidi ti mo fi n lu iyawo mi atawọn ọmọ to bi fun mi nigba gbogbo- Lukuman

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Mallam Isiyaku Abdul Rahman, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ Sharia  kan to wa lagbegbe Magajin-Gari, nipinlẹ Kaduna, ni awọn tọkọ-taya meji kan, Ọgbẹni Lukuman Ṣọladoye, ati Abilekọ Kẹmi Ṣọladoye, wọ ara wọn lọ. Abilekọ Kẹmi lo pe ọkọ rẹ, Ọgbẹni Lukuman, lẹjọ sile-ẹjọ ọhun, ẹsun to fi kan an ni pe igba gbogbo lo fi maa n lu oun atawọn ọmọ mẹrin toun bi fun un. Obinrin yii ni ohun ti oun n fẹ bayii ni pe ki adajọ ile-ẹjọ ọhun tu igbeyawo ọdun to wa laarin awọn mejeeji ka loju-ẹsẹ, ki kaluku awọn si maa lọ layọ ati alaafia.

Agbẹjoro Abilekọ Ṣọladoye, B.A Tanko, to gba ẹnu iyaale ile naa rẹ sọrọ nile-ẹjọ  sọ pe onibaara oun n fẹ ki adajọ ile-ẹjọ ọhun tu igbeyawo to wa laarin awọn mejeeji ka.

Ṣugbọn ṣe lọrọ ọhun ya gbogbo awọn to wa nile-ẹjọ naa lẹnu nigba ti Kẹmi maa sọrọ, ohun to sọ ni pe oun ti ṣaforiji fun ọkọ oun, oun si ti yi ipinu ọkan oun pada lori igbesẹ to gbe oun wa sile-ẹjọ naa.

O ni ‘Oluwa mi, mo ti foriji ọkọ mi, emi ni mo gbẹjọ rẹ wa sile-ẹjọ tẹlẹ pe ki wọn tu igbeyawo to wa laarin awa mejeeji ka, ṣugbọn mo tun ti da a ro pe, ka a jọ maa gbe pọ gẹgẹ bi tọkọtaya, ṣugbọn ohun kan ṣoṣo ti ẹ maa ṣe fun mi ni pe kẹ ẹ ba mi ki i nilọ pe ko gbọdọ gbọwọ rẹ soke mọ lati lu mi. Eyi gan-an lo mu mi fẹẹ kọ ọ silẹ tẹlẹ. Igba gbogbo lo maa n lu emi pẹlu awọn ọmọ mẹrin ti mo bi fun un, ki i tiẹ ro pe ọjọ  ti pẹ ti awa mejeeji ti fẹra wa sile. Igbaju-igbamu lo fi maa n ṣe temi niwaju awọn ọmọ wa, bẹẹ lo maa lu awọn ọmọ naa bajẹ bi wọn ba ṣẹ ẹ lẹṣẹ kekere ninu ile, gbogbo iwa radarada wọnyi ni mo fẹ ko lọọ wa ọwọ rẹ bọlẹ pata.

Nigba ti ọkọ obinrin yii n fesi si ohun to sọ yii, o ni, ‘Oluwa mi, ki i ṣe pe emi paapaa maa n deede lu iyawo mi yii atawọn ọmọ to bi fun mi nigba gbogbo, ṣugbọn mo maa n lu wọn bajẹ nigba ti wọn ba ṣẹ ẹṣẹ nla ni, mo si n lu wọn lati tọ wọn sọna to daa ni. Ko ni i daa rara kawọn araadugbo maa tọka si wọn nita pe iyawo lagbaja tabi ọmọ lagbaja lo n ṣiwa-hu nita yẹn, idi niyi ti mo fi n fi lilu kọ wọn lẹkọọ ninu ile, ki wọn ma baa tabuku mi nita. Ẹkọ ni lilu ọhun jẹ fun wọn, mi o ni i laju mi silẹ ki aye wọn waa bajẹ niwaju mi rara’.

Ninu idajọ rẹ, adajọ gba Ọgbẹni Lukuman nimọran pe ki i ṣe lilu nigba gbogbo ni ọna kan ṣoṣo ti obi tabi alagbatọ fi le kọ awọn ọmọ wọn lẹkọọ ninu ile, o rọ olujẹjọ pe ko maa gbiyanju lati maa pe iyawo rẹ ati awọn ọmọ rẹ si akiyesi nigba gbogbo ti wọn ba ṣiwa-hu ninu ile. Bakan naa ni adajọ ile-ẹjọ ọhun ni awọn yoo maa ṣọ gbogbo bi olujẹjọ atawọn ẹbi rẹ ṣe n gbe papọ ninu ile lati akoko yii lọ.

O sun igbẹjọ siwaju dọjọ miiran.

Leave a Reply