Bureeki mọto ayọkẹlẹ feeli, o ja wọle onile, eeyan mẹrin lo run mọlẹ

 Adewale Adeoye

Eeyan mẹrin ti mọto ayọkẹlẹ kan run mọlẹ gidi ninu iyara ti wọn n sun si ni wọn wa l’ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii nileewosan ijọba nibi ti wọn ti n gbatọju lọwọ.

Mọto ayọkẹlẹ ọhun to jẹ alawọ funfun lo sọ ijanu ọkọ rẹ nu iyẹn bureeki to si lọọ ya baara wọnu ile tawọn onitọhun sun si lọwọ to si ṣe wọn ṣikaṣika lati oju oorun ti wọn wa.

Iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye lagbegbe Liasu niluu, Idimu, nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe, laarọ kutukutu ọjọ Aiku Sanndee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii ni iṣẹlẹ laabi ọhun ṣẹlẹ ni nnkan bi aago marun-un idaji ọjọ naa.

Ere asapajude wa lara ohun tawọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ sọ pe lo fa ijamba naa. Wọn ni gbara ti dẹrẹba ọkọ ọhun dewaju ṣọọṣi Katoliiki kan to wa lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lo ti sọ ijanu ọkọ rẹ nu ti bureeki mọto ọhun si daṣẹ silẹ lojiji, gbogbo akitiyan dẹrẹba ọkọ ọhun lati fori mọto naa ti sibi to daa lo ja si pabo nitori pe, ere to n sa bọ ki i ṣe kekere rara. nigba ti ko si tete ribi gidi to maa fori ọkọ ọhun ti si lo ba kọju rẹ sinu ṣọọbu kan ṣugbọn ti mọto ọhun pada jade lodikeji ṣọọbu ọhun to si lọọ bawọn alabaru kan to n sun inu ile kan lẹyin ṣọọbu naa, tawọn mẹrin lara awọn mẹẹẹdogun to wa ninu ile naa si farapa yannayanna nitori pe, oju oorun ni iṣẹlẹ ọhun ti ba wọn ati pe ojiji ni iṣẹlẹ ọhun waye si wọn.

Ọkan l’ara awọn araadugbo nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Ọgbẹni Sodiq Aderẹmi ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ to gba lati ba oniroyin sọrọ sọ pe awọn alabaaru kan ti wọn n bawọn ṣiṣẹ ninu ọgba to wa nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni mọto naa lọọ ya ba ninu ile.

O ni ‘Lati ibudokọ Council niluu Idimu ni mọto ọhun ti n bọ, ṣugbọn gbara ti bureeki rẹ feeli lo ti n wa ibi to maa da mọto naa bọ ọpẹlọpẹ pe opo ina NEPA to wa niwaju ṣọọbu yii to gba mọto naa duro ni ko jẹ ki ijamba naa pọ ju bo ṣe yẹ lọ.

Gbara ti iṣẹlẹ naa waye ni awakọ mọto naa atawọn meji kan ti wọn wa pẹlu rẹ ti fẹ sa lọ, wọn mu dẹrẹba ọhun nigba tawọn ọrẹ rẹ meji yooku sa mọ awọn araadugbo naa lọwọ, wọn fọwọ ba a diẹ  fohun to ṣe ko too di pe, wọn fa le awọn ọlọpaa lọwọ.

Leave a Reply