Ọrọ iyọnipo adajọ agba Ọṣun tun di wahala, tajutaju lọlọpaa fi tu awọn oṣiṣẹ kootu ka

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu nipinlẹ Ọsun ti kede pe awọn ti bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ bayii. Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọlọpaa ṣe fi gaasi tajutaju tu wọn kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko ti wọn n fẹhonu han niwaju ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Oṣogbo.

Ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ oṣu yii, ni wọn ti bẹrẹ ifẹhonu han lori ohun ti wọn pe ni aye alabata ti adajọ agba nipinlẹ Ọṣun,  Onidaajọ Adepele Ojo n jẹ.

Wọn ni awọn ko ni i ṣiwọ ifẹhonu han naa titi ti Adepele yoo fi san gbogbo ẹtọ awọn fun awọn, ti yoo si gba awọn oṣiṣẹ to da duro lọna aitọ pada.

Ṣugbọn laaarọ ọjọ Wẹsidee ni Onidaajọ Adepele wọ inu ọgba ile-ẹjọ naa, eleyii to bi awọn oṣiṣẹ naa ninu, bi wọn ṣe n sun mọ ibi ti dẹrẹba paaki mọto rẹ si lawọn ọlọpaa da gaasi tajutaju bolẹ lati le wọn.

Bayii lọrọ di bo o lọ o ya lọna, idi si niyi ti alaga awọn oṣiṣẹ naa, Gbenga Eludire, fi kede pe iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ ti bẹrẹ bayii, ko si si oṣiṣẹ ẹka naa kankan to gbọdọ lọ sibi iṣẹ.

Ṣugbọn ọtọ loju ti awọn kan to ba akọroyin wa sọrọ nipa ifẹhonu han naa fi wo bi nnkan ṣe n lọ. Okunrin kan to pera ẹ ni Olugbenga Ogundeji sọ fun akọroyin wa pe oṣelu lo wa nidii gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ọhun. O ni nibo lawọn oṣiṣẹ ọhun foju si lati ọjọ yii ti wọn ko daṣẹ silẹ, to waa jẹ pe nigba ti ijọba Ọṣun yọ adajọ agba naa ni wọn too mọ pe o ṣẹ wọn lẹse kan, tabi pe o fi ẹtọ wọn du wọn. O ni iromi awọn oṣiṣẹ to n fa wahala yii wa labẹ omi ni.

 

Leave a Reply