Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Ọbantoko, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lawọn ti bẹrẹ iwadii lori b’awọn afini ṣoogun owo kan ṣe pa ọdọmọdekunrin kan to n jẹ John Ṣoyinka, ọmọ-ọdun mejila pere lagbegbe Kotogbo, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, laipẹ yii.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin bayii lawọn ẹgbẹ lanlọọdu, nibi ti oloogbe naa ati iya rẹ n gbe ti n wa ọmọkunrin ọhun kaakiri nigba ti wọn ko mọ bo ṣe poora kuro ni ṣọọbu kan to ti n ba wọn taja. Latigba ti wọn ti n wa a ni awọn ẹgbẹ lanlọọdu ọhun ti lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa Ọbantoko leti.
Ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, ọsẹ yii, ni awọn kan ri oku ọmọ ọhun ninu igbo kekere kan to wa laduugbo Kotogbo, lagbegbe ibi ti ọmọ ọhun n gbe. Wọn ti yọ oju rẹ, ti wọn si tun ti ge ọwọ rẹ mejeeji lọ. Eyi lo mu kawọn to ri i bi wọn ṣe ṣe ọmọ ọhun ṣikaṣika sọ pe awọn apani ṣetutu ọla lo lo ọmọ ọhun fun oogun owo.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe ibi ti iṣẹlẹ laabi naa ti ṣẹlẹ ṣalaye pe oun mọ ọmọ naa daadaa nigba aye rẹ, ati pe ọmọ ọhun ki i wọn lẹyin iya rẹ, oun pẹlu rẹ ni wọn jọ maa n lọ kaakiri nigba gbogbo ko too di pe wọn ko ri i lati nnkan bii ọsẹ kan sẹyin bayii.
‘‘Bi mo ṣe n wo o, o jọ pe iya ọmọ ọhun ko si nile ọkọ to bimọ ọkunrin ọhun fun. Oun ati ọmọ ọhun ni mo saaba maa n ri nigba gbogbo, iṣẹ awọn to n baayan tun ile ṣe niya ọmọ naa n ṣe kaakiri adugbo yii, ti wọn aa si fun un lowo lẹyin to ba pari iṣẹ rẹ tan. Ọmọ rẹ yii naa maa n ba awọn to ni ṣọọbu kan ṣiṣẹ ni, o maa n ran wọn lọwọ lati da kọsitọọma to ba fẹ waa gbowo pẹlu ATM iyẹn P.O.S lohun nigba to ba de lati ileewe.
‘‘Ẹnikan lo waa gbowo lọwọ wọn lọjọ ti ọmọ ọhun maa poora, o sare tẹlẹ onitọhun lẹyin ni gbara ti wọn ko ri owo fun un, bo ṣe di pe wọn n wa a niyẹn o. Gbogbo awọn to mọ ọmọ naa ati iya rẹ ni wọn wa a lọjọ yii, nigba ti wọn ko ri i lawọn ẹgbẹ lanlọọdu adugbo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan to wa ni Ọbantoko, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun leti. Awọn naa gbiyanju latigba ta a ti n wa ọmọ ọhun, ko too di pe wọn ri oku rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ninu igbo kekere kan to wa lagbegbe ibi ti ọmọ naa n gbe bayii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun S.P Ọmọlọla Odutọla to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ pe loootọ ni wọn n wa ọmọ naa, ṣugbọn to jẹ pe ọjọ Aje, ọsẹ yii ni wọn too ri oku rẹ nibi tawọn to pa a ju si.
O ni awọn maa too bẹrẹ iwadii nipa rẹ, tawọn si maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn ọdaran to lọwọ ninu iku ọmọ ọhun laipẹ.