Adewale Adeoye
Ni bayii, ọkan pataki lara awọn agbẹjọro ijọba ipinlẹ Eko to n ri sọrọ ẹjọ gbajumọ olorin hipọọpu nni, Oloogbe ilerioluwa Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad, Lọọya O Akinde, ti sọ fawọn adajọ ile-ẹjọ Korona to n gbẹjọ iku to pa oloogbe naa ni Ita-Ẹlẹwa, niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko, pe loootọ awọn ti pari ayẹwo ita sara oloogbe naa, ṣugbọn ayẹwo inu to maa sọ ohun gan-an to pa oloogbe naa n lọ lọwọ lorileede Amẹrika bayii, ati pe, o digba tawọn oniṣegun oyinbo ti wọn n ṣiṣẹ lori rẹ ba sọ esi abajade wọn nipa rẹ lawọn too le sọ ohun gan-an to pa oloogbe naa faraye gbọ.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla yii, nigbẹjọ miiran tun waye lori ẹjọ tawọn adajọ ile-ẹjọ Korona ọhun n gbọ lori iku oloogbe naa niluu Ikorodu.
Agbẹjọro Akinde ko si ṣiye meji rara lati sọ gbangba niwaju Onidaajọ Adetayọ Shotobi tile-ẹjọ Korona ọhun atawọn agbẹjọro yooku ti wọn wa ni kootu naa pe esi ayẹwo tawọn dokita ilu oyinbo n ṣe lọwọ nilẹ Amẹrika gan-an lo n da ikede ohun to pa oloogbe naa duro bayii.
Bẹẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Abilekọ Olumiyi ti i ṣe iya oloogbe naa kigbe tantan, to si n sọ pe Alagba Joseph Alọba ti i ṣe baba oloogbe naa ni ko jẹ kawọn ti i ṣeto isinku ọmọ oun, to si ni kawọn ọmọ orile-ede Naijiria ba oun bẹ ẹ pe ko jọwọ oku oloogbe naa silẹ fawọn ọrẹ rẹ gbogbo lati ṣẹyẹ ikẹyin fun un, ko le lọọ sinmi lọdọ ẹlẹdaa rẹ.
Ṣugbọn pẹlu ohun ti lọọya ijọba Eko sọ ni kootu yii, o ṣee ṣe ko jẹ pe ki i ṣe baba oloogbe gan-an lo n da eto isinku ọmọ rẹ duro rara, bi ko ṣe pe nitori pe wọn ko ti i pari ayẹwo sokuu oloogbe naa bayii.