Monisọla Saka
Adura Alọba, ti i ṣe aburo ati ọmọ ti wọn bi le oloogbe Ilerioluwa Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad, ti darukọ ẹni to ni o da oun loju pe o pa bọọda oun.
Niwaju awọn igbimọ ti wọn n wadii iku to pa Mohbad, nile-ẹjọ to wa ni agbegbe Ita-Ẹlẹwa, Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni Adura ti la a mọlẹ pe ọrẹ ati kekere ẹgbọn oun, ẹni ti wọn n pe ni Primeboy, lo gbẹmi Mohbad.
“Aburo Mohbad gangan ni mi. Ọmọ ogun ọdun ni emi. Oun ni ọmọ ẹlẹẹkeji, nigba ti emi jẹ ẹlẹẹkẹta. Ọdọ ẹgbọn mi atiyawo ẹ ni mo n gbe. Wọn maa n ja gan-an ninu ile, lọpọ igba si niyi, baba mi lo maa n waa ba wọn yanju ẹ. Wọn tun ja ija kan ṣaaju ere ti Mohbad ṣe kẹyin niluu Ikorodu, amọ emi o si nibẹ nigba toun ati Primeboy n ja. Wumi lo pada sọ fun mi pe wọn ja. Ti wọn ba ni ki n mu olori afurasi lori ẹni to pa ẹgbọn mi, Primeboy ni.
“Bo tilẹ jẹ pe mi o si nibẹ lasiko ti wọn ja, gbogbo bi ọrọ ṣe lọ ni Wumi ṣalaye fun mi pata, mo si gba a gbọ. Nigba ta a dele lẹyin ere to lọọ ṣe, isalẹ lemi wa nigba ti gbogbo wọn ti goke lọ. Nigba to ya ti mo fẹẹ lọọ fun ẹgbọn mi ni foonu ẹ ninu yara ẹ, ori ariwo ati ariyanjiyan ni mo ba awọn atiyawo wọn nitori fisa Canada.
“Ki nọọsi too wa rara, gaga ni ara bọọda mi ya, bo tilẹ jẹ pe mo ri ipa ẹjẹ ni ẹgbẹ igunpa ẹ lọjọ Tusidee. Emi ni mo ṣe Indomie ti gbogbo wa jẹ lọjọ naa. Lori ọrọ pe ẹgbọn mi ni arun ọpọlọ, irọ pata gbaa ni o. Kokooko lara rẹ le, ko si si ọrọ pe o ti ni gan-an-gan-an-gan ri. Primeboy lo pa ẹgbọn mi o”.
Bayii ni Adura, aburo Mohbad ṣalaye niwaju awọn to n ṣewadii iku ẹgbọn ẹ.