Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọga ileeṣẹ aladaani kan, Ọgbẹni Isiaka Saheed, ti wọ meji ninu awọn oṣiṣẹ ẹ lọ siwaju EFCC, iyẹn ajọ to n gbogun ti magomago owo ati iwa jibiti, o ni wọn ja oun lole ọja olowo rẹpẹtẹ.
Awọn oṣiṣẹ ọhun, Lateef Jamiu Babatunde
ati Oyetunde Abioye Ibrahim, ni wọn fẹsun ole ati iwa jibiti kan, wọn ni wọn fẹẹ fọbẹ ẹyin jẹ ileeṣẹ wọn niṣu.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn mẹtẹẹta wọnyi l’Ọgbẹni Saheed, ti i ṣe oludasilẹ ileeṣẹ olokoowo kan n’Ibadan, ran niṣẹ gẹgẹ bii oṣiṣẹ ẹ, o ni ki wọn gbe kòkó gbigbẹ lọ si ebute Tin Can, lagbegbe Apapa, l’Ekoo, ṣugbọn to jẹ pe niṣe ni wọn gbe ọja naa gba ibomi-in lọ.
Eyi lo mu ki ọga wọn lọọ fọrọ naa to awọn EFCC lẹti. Lẹyin iwadii wọn lajọ naa gbe awọn afurasi ole naa lọ si ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan.
Ṣaaju lọwọ ajọ naa ti tẹ ẹni ti wọn ta koko ọhun fun, Ọlanipẹkun Ọlawale Joseph. Atoun, atawọn to ta ọja ole ọhun fun ni wọn jọ fi panpẹ ọba gbe, ti wọn si jọ pe lẹjọ siwaju Onidaajọ
Adebukọla Ọlajide nile-ẹjọ giga naa.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ole ati iwa jibiti ni EFCC fi kan awọn mẹtẹẹta nile-ẹjọ.
Ọkan ninu awọn ẹsun ọhun ti wọn ka si eyi to n jẹ Joseph ninu awọn olujẹjọ naa leti ni pe “iwọ Ọlanipekun Ọlawale Joseph, lọjọ kẹrilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, o gba koko ti iwọn rẹ to tọọnu mẹtalelọgbọn ati diẹ (33.6 tons), to jẹ ti ileeṣẹ Olam Nigeria Limited, ti iye owo ẹ si n lọ bii miliọnu lọba ẹgbẹrun mejidinlọgọrun-un Naira (N97, 578, 000). Eyi lodi si ofin ipinlẹ Ọyọ, ti ọdun 2000, eyi to ṣe iwa ọdaran leewọ, to si la ijiya lọ”.
Ko sẹni to gba pe oun jẹbi ẹsun ọdaran wọnyi ninu awọn mẹtẹẹta. Eyi lo mu ki Amofin Damilare Ọdẹmuyiwa, ti i ṣe agbẹjọro EFCC, rọ ile-ẹjọ lati fun wọn lọjọ ti igbẹjọ naa yoo bẹrẹ, nigba naa loun yoo jẹ ki awọn olujẹjọ naa mọ pe ọran ti wọn da ọhun lodi sofin ijọba.
Lẹyin ti Amofin Alabi Ogor, ti i ṣe agbẹjọro awọn olujẹjọ ti bẹbẹ fun beeli wọn, Onidaajọ Ọlajide, gba beeli awọn olujẹjọ mẹtẹẹta pẹlu oniduuro meji.
Gẹgẹ bii majẹmu beeli ọhun, awọn oniduuro mejeeji gbọdọ ni iṣẹ gidi lọwọ to bẹẹ, ti ọkọọkan wọn fi gbọdọ ni ikapa lati san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (₦100, 000), iyẹn bi awọn olujẹjọ ti wọn ṣe oniduuro fun ba kọ lati yọju si kootu nigbakuugba to ba yẹ ki wọn yọju sile-ẹjọ.