Oju ole ree: Ẹ woju gende-kunrin to n ji ẹran ẹlẹran gbe laarin ilu

Adewale Adeoye

Gende-kunrin kan lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue ti tẹ bayii, lori ẹsun ole jija. Ẹran ẹlẹran ni wọn lo maa n ji gbe laarin ilu, ti yoo si lọọ ta a lowo pọọku fawọn eeyan.

ALAROYE gbọ pe o ti pẹ ti wọn ti n huwa buruku naa ko too di pe aṣiri wọn tu, ti wọn si ri wọn gba mu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ojo kẹtalelogun, oṣu Kọkanla yii, ti wọn si ba ẹran to ji gbe lọwọ rẹ.

Ewurẹ pẹlu ẹran obukọ ni wọn lo maa n ji gbe ko too di pe ọwọ awọn ọdọ adugbo tẹ ẹ, wọn ti kọkọ fi iya nla jẹ ẹ, wọn ti lu u daadaa ko too di pe wọn fa a le awọn agbofinro agbegbe ibi to ti ṣiwa-hu naa lọwọ pe ki wọn ba a fẹsẹ ofin to ọrọ rẹ.

Okan lara awọn olugbe agbegbe naa sọ pe ọrọ ọmọkunrin naa jẹ iyalẹnu soun nitori  ṣe lo yẹ ko gbiyanju lati waṣẹ gidi ṣe tabi ko maa ṣiṣẹ alabaaru kaakiri igboro, dipo bo ṣe n lọọ ji ẹran ẹlẹran gbe yii.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe ọhun ti lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ nitori pe ọpọ igba lawọn araalu ti w aa fẹjọ  sun pe awọn ko ri awọn ẹran tawọn n sin mọ. Wọn fi kun un pe awọn maa ibi to n ta awọn ẹran ọhun si, tawọn si maa mu awọn onibaara rẹ naa, ki gbogbo wọn pata le jiya ẹṣẹ wọn.

 

Leave a Reply