Ileegbimọ aṣofin gbe abọ iwadii jade lori Onidaajọ Adepele Ojo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Igbimọ ti Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Adewale Ẹgbẹdun, gbe kalẹ lati ṣewadii oniruuru ẹsun ti wọn fi kan adajọ-agba, Onidaajọ Oyebọla Adepele Ojo, ti jabọ iwadii wọn.

Alaga awọn aṣofin lori ọrọ ẹka eto idajọ ati ọrọ ofin, Ọnarebu Kanmi Ajibọla, ṣalaye pe ofin orileede Naijiria fun awọn aṣofin lagbara lati ṣewadii ẹnikẹni ti wọn ba fẹsun kan, paapaa, nigba to jẹ pe awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun ni ọrọ yii kan, to si jẹ pe ileegbimọ aṣofin lo buwọ lu owo ti wọn sọ pe wọn ṣe baṣubaṣu yii.

Ajibọla sọ siwaju pe laarin ọjọ meje ti ileegbimọ fun awọn lanfaani lati ṣiṣẹ iwadii ọhun, igbimọ naa ranṣẹ si awọn ti wọn kọ iwe ẹsun nipa Adepele, bẹẹ lawọn tun fi iwe ipe ranṣẹ si awọn kan, ninu eyi ti a ti ri adele akọwe agba kootu, alakooso inawo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu akọsilẹ abọ iwadii oju-ewe mẹjọ ti igbimọ Ajibọla gbe ka iwaju awọn aṣofin naa ni wọn ti ṣakiyesi pe awọn oṣiṣẹ kan wa ti adajọ agba da duro lẹnu iṣẹ lọna aitọ.

Yatọ si pe oniruuru igbimọ ti adajọ agba gbe kalẹ lati wadii ẹsun ti wọn fi kan awọn oṣiṣẹ yii, titi to fi de ọdọ ajọ ICPC ko ri ẹri kankan lati fi fiya jẹ wọn, sibẹ, Onidaajọ Ojo ko gba wọn pada.

Bakan naa ni adajọ-agba yii gbe iṣẹ ibura lori ẹrọ ayelujara, e-affidavit, fun akọṣẹmọṣẹ lai gba aṣẹ lati ọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun, ti ko si si akọsilẹ adehun kankan pẹlu ajọ to n pawo wọle labẹnu funjọba, iyẹn, Ọṣun Internal Revenue Service (OIRS).

Ninu rẹ tun ni aigbọran si aṣẹ ile-ẹjọ lati san owo ti wọn gba lọwọ awọn adigunjale ti wọn fọ banki niluu Ikirun sinu asunwọn ijọba, ti Adepele si ni ki wọn san owo naa si akanti kootu.

Ṣiṣe owo tijọba n san si ẹka eto idajọ baṣubaṣu, to fi mọ kiko owo to tọ si onidaajọ kan nipinlẹ Ọṣun jẹ.

Abọ iwadii yii ati awọn ẹri ti awọn ti wọn kọwe ẹsun nipa Adepele ni igbimọ ile aṣofin dabaa pe ki wọn fi ranṣẹ si Gomina Ademọla Adeleke, ki gomina si ko wọn ranṣẹ si ajọ to n ri si iṣakoso ẹka idajọ, iyẹn NJC.

 

Leave a Reply