Faith Adebọla
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ to n ṣoju ijọba ilẹ United Kingdom, (UK), nilẹ wa, iyẹn Ẹmbasi UK, to wa niluu Abuja, ti ri pipọn oju gbajugbaja olorin hipọọpu tawọn ọdọ fẹran nni, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable olorin. Ki i ṣe pe ọkunrin to fẹran lati maa daṣa ‘wahala wahala wahala’ yii n binu si ẹmbasi UK nikan kọ, niṣe lo tun n fibinu sọko ọrọ si wọn loriṣiiriṣii, to si n leri pọn-ọn-ran-pọn lati fi aidunnu rẹ han.
Ninu fọran fidio kan to gbe sori ayelujara, Habeeb to maa n pe ara ẹ ni Ika of Africa yii ni oun fẹẹ lọ ṣere niluu London, atawọn ilu mi-in lorileede United Kingdom, wọn si ti lu paali oun, iyẹn fisa toun yoo fi wọ ilu naa lontẹ. O ni oun ko le da nikan lọ siru ode ere nla bii eyi, oun gbọdọ mu iyawo oun dani, tori bawọn elere ṣe maa n ṣe niyẹn. Amọ iyalẹnu lo jẹ foun nigba ti wọn sọ foun pe awọn alaṣẹ Ẹmbasi UK ko lu paali tiyawo oun, wọn ko fọwọ si i pe kawọn jọ rinrin-ajo naa, wọn ko si fun un ni fisa. Eyi lo fa ibinu Portable, Idaamu Adugbo ọmọ Ọlalọmi.
Bi Portable ṣe n lọgun sọrọ, bẹẹ lo n ranju wan-an, o ni: ‘‘Ṣe ẹ n waini mi ni? Naijiria gan-an ti pawo bayii, lojumọ ti mo ba ṣe show ni Naija, ti mo gba five five miliọnu mẹwaa, fun ọjọ mẹwaa ti mo fẹẹ lọọ lo ni Lọndon, ṣe ẹ o mọ iye ti iyẹn jẹ nibi ni?
“Mo wa n lọ si UK, wọn o ti i… Ha, wọn ti lu paali mi o, wọn lu paali mi o, amọ wọn o lu ti iyawo mi o. Ẹ ma ti i buuku flight o, ẹ ma ti i sanwo wiwọ baaluu o, emi atiyawo mi la jọ maa lọ o. O wa ninu adehun wa pe emi atiyawo mi ni o, ẹ ba mi sọ fun Biliqeu, Biliqeu, ki wọn buuku flight iyawo mi, Aa, ti wọn ba ti lu paali mi, ki lo de ti wọn ko lu tiyawo mi mọ ọn, mi o gba o. Iyawo mi ko ni wahala, emi ni gangster, ti wọn ba ti lu mi, wọn maa lu tiyawo mi, wọn o lu paali iyawo mi, niṣe ni wọn mu pasipọọtu iyawo mi, wọn sọ ọ ṣegbẹẹ ni o. Wọn fẹẹ rip mi ni o, wọn fẹẹ lo wayo fun mi ni o. Mo dẹ ti sọ fun wọn tẹlẹ pe emi atiyawo mi la jọ n lọ o, a fẹẹ lọọ ṣe famili ni, mo fẹẹ lọọ ẹnjọyi aye mi ni, ki n waa gba ibẹ wọ show. Wahala ti de o, mi o gba o.”
Ninu fidio mi-in, Portable tun parọwa sawọn ololufẹ rẹ ni London, pe ki wọn ba oun da sọrọ to ṣẹlẹ yii, tori oun atiyawo oun lawọn gbọdọ jọọ lọ, o loun ko fẹẹ de London koun maa waa lọ gbe aṣẹwo sun, ‘I no fit do hook up abroad’, gẹgẹ bo ṣe sọrọ ọhun.
Ninu fidio mi-in ẹwẹ, wọn ṣafihan Portable bo ti ṣe balẹ sorileede UK, nibi to ti n fi kẹkẹ kan ti awọn baagi ati ẹru rẹ jade ni ẹẹpọọtu London, amọ iyawo rẹ ko si lẹgbẹẹ rẹ, bẹẹ lawọn ololufẹ rẹ kan ti wọn waa pade rẹ n fi i ṣe yẹyẹ pe iyawo rẹ ko tẹle e wa, amọ Portable fesi fun wọn pa eto ti n lọ lori ti iyawo oun, o ni Ọmọbẹwaji Ẹwatomi maa waa ba oun laipẹ.
Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan kọ nipa fidio yii. Bawọn ololufẹ rẹ kan ṣe n kaaanu rẹ, ti wọn si n beere boya awọn iwe kan wa to yẹ kiyawo rẹ ọhun fun wọn lẹmbasi ti ko fun wọn, bẹẹ lawọn mi-in n bẹnu atẹ lu Portable fun bo ṣe n lọgun, to si n fi itara gba teburu iwaju rẹ, ati awọn iwa jagidijagan to ṣafihan rẹ. Ẹnikan tiẹ beere lọwọ rẹ pe ṣe ogun laye ni, ṣe gbogbo ọrọ tiẹ lo maa maa la ariwo ati ijangbọn lo ni?