Ọwọ tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n daamu wọn ni Sango-Ọta

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa kan to wa niluu Sango-Ọta, nipinlẹ Ogun, lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta kan wa ti wọn ti n ran awọn ọlọpaa teṣan ọhun lọwọ lori ọna ti wọn maa gba lati ri awọn ẹlẹgbẹ wọn yooku mu.

Bakan naa lawọn ọlọpaa lawọn maa too foju gbogbo awọn ẹni tawọn ba ri mu lori ọrọ ẹgbẹ okunkun laarin ilu naa bale-ẹjọ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta tọwọ tẹ ni: Ahmed Oguntoyinbo, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Sikiru Kọmọlafẹ, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Abiọla Alashebi, ẹni ọgbọn ọdun.

ALAROYE gbọ pe ipade ẹgbẹ okunkun Aye lawọn ọmọ ẹgbẹ naa fẹẹ ṣe, ati pe owuyẹ kan lo ta awọn ọlọpaa agbegbe Sango-Ọta lolobo nipa irin aw ọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun. Loju-ẹsẹ tawọn ọlọpaa ti gbọ nipa ipade aburu ọhun ni wọn ti bẹrẹ si i fimu finlẹ lati mọ ibi ti wọn ti maa ṣe e. Ko pẹ rara tawọn ọlọpaa fi mọ ibi ipade naa, ni wọn ba lọọ ka wọn mọ’bẹ ni nnkan bii aago mẹsan-an aṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii. Mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii lọwọ tẹ lasiko ti wọn n ṣepade ẹgbẹ wọn lọwọ. Ṣe lawọn ẹlẹgbẹ wọn yooku ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti wọn ko si ri wọn mu.

Ọdọ awọn ọlọpaa ti wọn wa ni wọn ti jẹwọ pe loootọ, ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye lawọn, ati pe ọjọ ti pẹ tawọn ti darapọ mọ ẹgbẹ okunkun ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, ti loun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe laipẹ yii lawọn maa foju gbogbo awọn tọwọ tẹ bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ ohun ti wọn mu wọn fun.

Leave a Reply