Eeyan mẹjọ ku, mẹfa fara pa, nibi ijamba ọkọ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

O kere tan, eeyan mẹjọ ni wọn ti dagbere faye, tawọn mẹfa miiran si fara pa yannayanna nibi ijamba ọkọ kan to waye lopopona Òkè-Onígbìn-ín, Òmù-Àrán, nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn, nipinlẹ Kwara.

Alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjo kẹrinlelogun, oṣu yii, ni ọkọ ero Mitsubishi  ati tirela Mack kan digbo lu ara wọn. Baale ile kan, abilekọ mẹta, awọn ọmọde mẹrin, ni wọn ku loju-ẹṣẹ, tawọn mẹfa miiran si fara pa yannayanna.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ ẹṣọ alaabo oju popo (FRSC), ni Kwara, SRC Busari Basambo, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, lo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Ẹti, Furaide, ọṣẹ yii, iṣẹlẹ buruku to gba omije loju ẹni ọhun ṣẹ, ero mẹjọ lo padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọhun, tawọn mẹfa mi-in si fara pa kọja sisọ.

O tẹsiwaju pe gbogbo awọn to fara pa ni wọn ti ko lọ si ile iwosan kan ti wọn n pe ni Ajísafẹ́, niluu Òmù-Àrán, fun itọju to peye, ti wọn si ti ko awọn oku lọ si yara igbokuu-si nileewosan Adéyẹmọ, niluu yii kan naa.

Basambo, ni ere asapajude ati yiya ara ẹni ṣilẹ lọna aitọ lo ṣokunfa ijamba naa.

Ọga agba ajọ ẹṣọ alaabo oju popo (FRSC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Dawulung, ni iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ijamba naa, o rọ gbogbo awọn awakọ ki wọn ye sare asapajude loju popo ki wọn si sọra fun irin-ajo alẹ.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni ajọ ẹṣọ alaabo ojupopo ko ni i kaaarẹ ọkan lati maa ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bo ṣe tọ ati bo ṣẹ lati ri i pe ijamba ọkọ dinku lojupopo.

Leave a Reply