Owo ele ti mo ya nitori ileewe awọn ọmọ mi lọkọ mi lọọ fi ṣekore ni ṣọọṣi, mi o ṣe mọ

 Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Abilekọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinle Ọyọ, lawọn tọkọ-taya meji kan, Abilekọ Oluwatoyin Ilọri ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Fẹmi Ilọri, gbe ara wọn lọ. Toyin lo gbẹjọ ọkọ rẹ lo sile-ẹjọ naa, ohun to si n beere lọwọ adajo ni pe ki wọn ba oun fopin si igbeyawo ọdun gbọọrọ to wa laarin oun ati ọkọ oun ni kia, ki kaluku awọn le maa lọ layọ ati alaafia.

Ninu ọrọ rẹ nile-ẹjọ naa lo ti sọ pe, ‘‘Oluwa mi, iya yii ti pọ ju fun mi, ṣe lọkọ mi kuna ninu ojuṣe rẹ ninu ile, gbogbo ohun to yẹ ko ṣe gẹgẹ bii ọkọ lori aya ati baba lori awọn ọmọ rẹ ni ko ṣe. Emi nikan ni mo n sare sọtun-un-sosi lori ki awọn ọmọ wa ma dero ẹyin. Ki i fun emi pẹlu awọn ọmọ ti mo bi fun un lowo ounjẹ rara, igba gbogbo lo si maa n lu mi bajẹ niṣoju awọn ọmọ yii.

‘‘Nigba miiran, aa tun fi ẹru mi sọko sita gbangba ni. Ọjọ kan tiẹ wa ti mo lọọ ya owo ele nita lẹyin tawọn alaṣẹ ileewe alakọọbẹrẹ kan tawọn ọmọ wa n lọ da wọn pada sile nitori ta a jẹ gbese to pọ gidi, ṣe lọkọ mi lọọ ji owo ọhun ko nibi ti mo tọju rẹ pamọ sí. Ṣe lẹnu ya mi nigba ti ọkọ mi n nawo bii ẹlẹda ni ṣọọṣi wa lasiko ajọdun ikore kan to waye gbẹyin, mi o mọ rara pe owo ileewe awọn ọmọ mi lo n na danu bẹẹ yẹn. Ko loju to n ti rara, ko sigba ti ki i gbeṣe rẹ de binu ba ti n bí i. Nigba to ya ni mo lọọ ko awọn ọmọ wa kuro nileewe ti wọn n lọ, nigba ti owo ta a n san nibẹ gara ju ohun ti emi nikan le maa san lọ, ṣugbọn ṣe lọkọ mi waa kọju ija si mi ni ṣọọbu kekere kan ti mo ti n taja, o lu mi bajẹ gidi ni to jẹ pe ọlọpaa lo ba wa da si i gbẹyin.

‘‘Ni kukuru, mo n rọ adajọ ile-ẹjọ yii pe ko tu igbeyawo ọlọdun gbọọrọ kan to wa laarin awa mejeji ka. Ki wọn ki i nilọ pe ko gbọdọ waa ba mi tabi halẹ mọ mi nibi ti mo n gbe mọ. Kile-ẹjọ faaye gba mi lati maa ṣetọju awọn ọmọ to wa laarin igbeyawo wa, ṣugbọn ko maa waa ṣojuṣe rẹ fawọn ọmọ naa loṣooṣu’’.

Nigba to maa fesi si ẹsun tiyawo rẹ fi kan an, Ọgbẹni Fẹmi gba pe ki adajo ile-ẹjọ naa tu igbeyawo to wa laarin awọn mejeeji ka, ṣugbọn o sọ pe irọ gbuu lo pọ ninu ẹsun tiyawo oun fi kan oun yii.

O ni, ‘‘Oluwa mi, emi paapaa fara mọ pe kile-ẹjọ tu igbeyawo to wa laarin wa ka, ṣugbọn irọ lo pọ ju ninu ọrọ ti iyawo mi waa sọ nile-ẹjọ yii. Mi o ki i lu nigba gbogbo gẹgẹ bo ṣe ti sọ yii, ṣugbọn lẹkọọkan ni mo maa n fọwọ ba a.

Adajo sun igbẹjọ si ọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun yii, o ni kawọn mejeeji ṣi maa gbe ni irẹpọ titi di akoko ti igbẹjọ maa waye lori ẹjọ wọn.

 

Leave a Reply