Adewale Adeoye
Gbogbo mọlẹbi ti file pọnti, wọn ti fọna roka, wọn si ti fi agbada dinran, bẹẹ ni tọkọ tiyawo naa, Ọgbẹni Isreal Kennedy ati Omidan Rose, ti ro dẹdẹ, ti wọn kan dudu, ero to waa ba wọn ṣẹyẹ naa ti wa ninu ṣọọṣi, ti wọn n jo ti wọn n yọ. Ṣugbọn pẹlu gbogbo imurasilẹ yii, igbeyawo ọhun ko papa waye. Niṣe lalufaa ijọ yari kanlẹ, o loun ko le so tọkọ-tiyawo naa pọ gẹgẹ bii lọkọ-laya. Ṣe lọrọ ọhun ya gbogbo awọn ẹbi, ara, ojulumọ, ọkunrin ati obinrin ti wọn wa lori ijokoo fun ti ayẹyẹ igbeyawo alarinrin to yẹ ko waye laarin awọn ololufẹ meji ọhun ni ṣọọṣi kan ti wọn n pe ni ‘Assemblies Of God Church’, to wa lagbegbe Ehere, niluu Ogbor-Hill, n’ipinlẹ Abia, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lẹnu, nigba ti alufaa ijọ ọhun, Ẹni-ọwọ Eze Ogba, yari kanlẹ pe lae, oun ko ni i so awọn ololufẹ meji ọhun pọ gẹgẹ bii tọkọ-taya nitori pe iyawo ti wa nipo iloyun. O ni ayẹwo tawọn dokita ṣe fun iyawo ọhun ṣaaju ọjọ ayẹyẹ naa fidi rẹ mulẹ pe oyun ti duro si i lara eyi to si ta ko ilana ṣọọṣi naa.
Pẹlu bi gbogbo awọn to wa fun inawo naa ṣe rawọ ẹbẹ si alufaa ijọ Ọlọrun naa pe ko ro ti owo ati wahala tawọn idile mejeeji ọhun ti ṣe lori ipalẹmọ ayẹyẹ ọhun, ati pe ko tun ro ti pe ọmọ ijọ ọhun lawọn mejeeji yii jẹ, ko so wọn pọ, alufaa ijọ naa ni ko s’ohun to jọ ọ. O ni o lodi sofin ijọ naa pe ki obinrin to ba fẹẹ ṣegbeyawo loyun ko too ṣe e. Bi iru eyi ba si ṣelẹ, wọn ko ni i so wọn pọ ninu ijọ Ọlọrun.
ALAROYE gbọ pe ọsẹ to kọja yii lo yẹ ki Ọgbẹni Isreal Kennedy ati Omidan Rose, ṣegbeyawo alarinrin ni ṣọọṣi ‘Assemblies Of God Church’ yii, ṣugbọn si iyalẹnu gbogbo ero ti awọn idile mejeeji yii ti fiwee pe fun ti ayẹyẹ ọhun, ṣe ni alufaa ijọ wọn ni ko sohun to jọ ọ. Alufaa ijọ naa lo kede rẹ lakooko tawọn alejo wa lori ijokoo pe oun ko ni i so awọn ololufẹ meji yii papọ nitori ipo iloyun tiyawo wa.
Awada lasan lawọn to wa lori ijokoo lọjọ naa kọkọ pe e, ṣugbọn nigba ti alabọrun n dewu si wọn lọrun ni wọn too mọ pe alufaa ọhun ko ṣere rara. Ẹyin eti rẹ ni gbogbo ẹbẹ pẹlu arọwa ti wọn n sọ lọjọ naa n bọ si fun un. Ori ohun to sọ naa lo duro le. Nigba to si han kedere pe alufaa ijọ naa ko ni i yi ipinu rẹ pada, tilẹ si ti n ṣu lawọn ẹbi mejeeji ba panu-pọ, ti wọn si sare lọ si ṣọọsi kekere kan ti ko jinna rara sibi ti wọn ti fẹẹ ṣegbeyawo ọhun tẹlẹ. Ṣọọṣi ajoji ọhun ni pasitọ ijọ ọhun ti so awọn ololufẹ mejeeji ọhun papọ gẹgẹ bii tọkọ-taya. Ninu ṣọọṣi ọhun lawọn ẹbi awọn tọkọ-taya yii si ti gbalejo, ti jijẹ ati mimu si waye nibẹ lai si wahala kankan rara.
Ọkan lara awọn ọmọ ijọ ibi ti alufaa ijọ wọn ko ti so awọn ololufẹ ọhun papọ ṣalaye fawọn oniroyin pe ko jẹ tuntun f’oun rara pe alufaa ijọ awọn ko so awọn ololufẹ meji yii pọ nitori pe o ti wa ninu ilana ati ofin ijọ awọn pe iyawo ko gbọdọ wa nipo iloyun ko too ṣegbeyawo, nitori rẹ lawọn ṣe maa n kan an nipa fawọn ololufẹ pe kiyawo kọkọ lọọ ṣayẹwo lati mo boya o wa ninu oyun ko too dọjọ igbeyawo rẹ. O ni ko si bi onitọhun ṣe le gbajumọ to laarin ilu, wọn ki i ni so ololufẹ meji tiyawo rẹ ba wa nipo iloyun papọ ninu ijo awọn rara.
Ṣa o, awọn ọmọ ijọ ọhun kọọkan tawọn naa ba awọn oniroyin sọrọ, ṣugbọn ti wọn ko fẹ ki orukọ wọn jade ninu iwe iroyin sọ pe ki i ṣohun to daa rara bi alufaa ijọ naa ṣe yari kanlẹ. Wọn ni o yẹ ko ro ti inawo ati wahala tawọn ololufẹ meji ọhun pẹlu tawọn ẹbi wọn ti ṣe, ko si ṣiju aanu wo wọn. Ati pe lẹyin ti wọn ba ṣegbyawo ọhun fawọn mejeeji tan ni ki wọn ṣẹṣẹ too da sẹria fun wọn.