Kayeefi, Pasitọ Sunday payawo ẹ toyun-toun l’Ekiti, wọn lo fẹẹ fi i ṣoogun owo ni

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọpọ awọn to gbọ ọrọ naa ni ko ti i gbagbọ, niṣe lọrọ naa si n ṣe awọn ọmọ ijọ pasitọ kan, Oluwadare Abiọdun Sunday, to ni ṣọọṣi ti wọn porukọ rẹ ni Mountain of Fire and Thunder Prayer Ministry, (Aara Ina), to wa ni Odo Ùrò, loju ọna Iyin, to lọ si ilu Ado Ekiti, niluu Ido Ile, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ni haa-in, nigba ti wọn gbọ pe  ọkunrin naa fun iyawo rẹ, Abilekọ Yẹmi Adetọla Ibironkẹ, to wa ninu oyun lọrun pa, ti obinrin naa si ku toyuntoyun.

Loootọ ni yoo ṣoro lati gbagbọ pe pasitọ ọhun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an yii, nitori ẹni to ba ri ọkunrin to ti figba kan jẹ babalawo, ṣugbọn to loun ti di iranṣẹ Ọlọrun ọhun bo ṣe n kuru, to n ga, lori pẹpẹ iwaasu, to si n gbadura kikankikan ni ṣoọṣi rẹ to pe ni Aara Ina yii, yoo ṣoro fun ọpọ eeyan lati gbagbọ pe iru ẹni bẹẹ ni yoo ṣeku pa iyawo rẹ.

Ṣugbọn wọn ni ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ni okunrin naa fun obinrin to wa ninu oyun yii lọrun pa.

ALAROYE Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ẹgbọn oloogbe naa ṣe ṣalaye, o ni iyalẹnu nla niṣẹlẹ naa jẹ fawọn pe ọkunrin to pera ẹ ni pasitọ yii le dan iru nnkan bẹẹ wo. O ni babalawo ni ọkunrin naa tẹlẹ ko too di pasitọ, nigba to ni Ọlọrun pe oun. Ṣugbọn iwa ata ti ko le fi ata silẹ ko jẹ ki Oluwadare gbadun, wọn ni niṣe lo n ku awọn ọmọ ijọ CAC to ti n ṣe pasitọ ni ori oke kan to wa ni Ekiti mọlẹ, bẹẹ ni wọn ni wọn ka oogun mọ ọn lọwọ, pẹlu awọn ẹsun mi-in loriṣiiriṣii, eyi to mu ki wọn le e kuro ni ori oke naa. Ni ọkunrin naa ba lọọ da ṣọọṣi tiẹ to pe ni Aara Ina silẹ.

Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ fun akọrin ALAROYE, ọkan ninu awọn ẹgbọn oloogbe naa ṣalaye pe, ‘‘Nnkan kan ko ṣe ọmobinrin naa, ọdọ iya rẹ lo wa lataarọ ọjọ naa to ti n ṣere titi di nnkan bii aago marun-un irọlẹ ti ọkọ rẹ ti wọn ni o ti rin irinajo kuro niluu naa lati ọjọ diẹ sẹyin fi pe  e lori foonu, tiyẹn si lọọ ba a.

‘‘Loju-ẹsẹ ni wọn ni o ti tọju ounjẹ fun un, ti ko si si ami kankan lara rẹ pe ohunkohun n ṣe e. Afi nigba to to bii aago mọkanla alẹ ti wọn ni ọkọ rẹ lọ sile ọkan ninu awọn ẹgbọn rẹ, to si ni ki wọn waa wo iyawo oun’’. ALAROYE gbọ pe nọọsi ni iyawo ẹgbọn ọmọbinrin yii. Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba to debẹ to yẹ obinrin naa wo, to si ri i pe o ti ku. Kayeefi ibẹ ni pe niṣe ni ẹjẹ n da lẹnu ati nimu obinrin naa, ti wọn si ni wọn fun un lọrun pa ni.

Baba naa ni, ‘‘Bi obinrin yii ṣe ri ohun to ṣẹlẹ to fẹẹ pariwo ni wọn ni pasitọ naa ni ko gbọdọ pariwo, eyi to mu ki tọhun sa jade. Ṣugbọn niṣe ni wọn ni pasitọ yii sa tẹlẹ e, to si n le e lọ. Ariwo ti obinrin naa mu bọnu lalẹ ọjọ yii ni wọn ni awọn eeyan fi jade sita, ni ọrọ ba di ranto.

‘‘Wọn ti gbe oku Ibironkẹ lọ si ileewosan ijọba to wa ni Ado-Ekiti, lati ṣe ayẹwo si oku rẹ, ki wọn le mọ iru iku to pa a’’.   

Leave a Reply