Lai fi ti bi ile-ẹjọ ṣe yọ ọ nipo ṣe, Ṣọun Ogbomọṣọ yoo ṣe ṣayẹyẹ iwuye

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lai fi ti pe ile-ẹjọ ti da a lọwọ kọ pe ko yee pe ara rẹ ni Ṣọun ti ilu Ogbomọsọ, toun naa si ti tun pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori eyi, ti igbẹjọ ọhun si n lọ lọwọ, Ọba Ghandi Afọlabi Laoye ti i ṣe Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ ti fẹẹ ṣe iwuye bayii.

Odidi ọsẹ kan gbako ni ọkan-o-jọkan eto yoo fi maa waye fun ayẹyẹ iwuye ọba naa, bẹrẹ lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 2023 yii,  ti yoo si maa lọ titi di Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindilogun (19), yii ko too wa sopin.

Alaga igbimọ ti wọn gbe kalẹ fun iwuye Ṣọun, eyi ti Ọjọgbọn Adeṣọla Adepọju lewaju rẹ lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu yii.

Àlàkalẹ̀ eto iwuye yii lo waye lẹyin ti ile-ẹjọ ti gba fun Ọba Ghandi lori ibeere to beere nile-ẹjọ pe ki adajọ dagunla si idajọ kan to waye laipẹ yii, eyi to rọ pasitọ ijọ Ridiimu nigba kan ri naa loye kuro ipo ọba.

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn (25), oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii, nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa niluu Ogbomọṣọ paṣẹ pe ki wọn le Ọba Ghandi kuro lori itẹ ọba Ogbomọṣọ.

Nigba to n ta ko iroyin kan to ti kọkọ kede ọjọ mi-in gẹgẹ bii ọjọ ayẹyẹ naa, Ọjọgbọn Adepọju, tẹnu mọ ọn pe laarin ọjọ kẹrinla, si ọjọ kọkandinlogun oṣu yii leto iwuye ọba ilu nla naa yoo waye.

O waa dupẹ lọwọ awọn oniroyin fun atilẹyin wọn nipa igbelarugẹ ipo ọba Ṣọun Ogbomọṣọ.

Leave a Reply