Eyi tun ga o, ọmọbinrin yii pa ọmọ tuntun jojolo to bi

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Sango-Ọta, nipinlẹ Ogun, ti mu ọdọmọbirin kan torukọ rẹ n jẹ Esther Ojuko, o si ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii ti wọn n ṣe nipa rẹ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o pa ọmọ ikoko kan to bi. Ohun to ṣe yii lawọn agbofinro ni o ta ko ilana ofin ipinlẹ naa patapata. Wọn lawọn maa kọkọ lọọ ṣayẹwo ọpọlọ fun un lati mọ boya o larun ọpọlọ lo ṣe hu iwa ọdaju bẹẹ sọmọ ikoko ọhun.

ALAROYE gbọ aṣiri ọmọbinrin naa tu lasiko ti oorun buruku gba gbogbo adugbo Oyede, niluu Sango-Ọta, nibi ti Ojuko n gbe, tawọn araalu naa ko si gbadun nitori ṣe lawọn eṣinṣin-ọdẹ nla n fo kaakiri. Nigba ti ko si alaafia kankan laarin agbegbe naa lawọn olugbe ibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ ba bẹrẹ si i wa gbogbo ayika wọn, ti wọn si pada ri oku ọmọ ikoko naa ninu apo ṣaka kan ti Ojuko ju u si, o ti n jẹra, o si ti n run.

Ọgbẹni Ogunmuyiwa ti i ṣe ọkan lara awọn olugbe agbegbe ọhun lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe Sango-Ọta leti, awọn ọlọpaa naa lo waa fọwọ ofin mu Ojuko ti wọn gbagbọ pe oun lo ṣiṣẹ laabi naa nitori ṣaaju akoko naa lo wa nipo iloyun, ṣugbọn ti ko si oyun ninu rẹ mọ bayii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjo Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, sọ pe oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe alaye toun gbọ nipa Ojuko ko jọ pe ara rẹ da rara.

O ni, ‘Mo ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, oorun lo tu aṣiri iṣẹ laabi ti Ojuko ṣe yii, ṣe lo ju ọmọ rẹ sinu apo ṣaka kan, to si ju u sọnu sile keji, awọn ọlopaa ti fọwọ ofin mu un, a maa too ṣayẹwo ọpọlọ fun un, ko jọ pe ara rẹ ya rara pẹlu ṣe n wo suu bi wọn ṣe n beere ọrọ lọwọ rẹ. Lẹyin iwadii wa la maa too foju rẹe bale-ẹjọ lori ohun to ṣe.’

Leave a Reply