Palietiifu: Adeleke kede afikun ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira fawọn oṣiṣẹ ijọba

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati le mu itura ba awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, Gomina Ademọla Adeleke ti kede ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira gẹgẹ bii afikun owooṣu fun awọn oṣiṣẹ ijọba.

Bakan naa lo kede afikun ẹgbẹrun mẹwaa Naira fun awọn oṣiṣẹ-fẹyinti kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti Agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, fi sita ṣe sọ, odidi oṣu mẹfa ni ijọba yoo fi san owo naa.

O ni oṣu Kejila, ọdun yii, ni afikun owo-oṣu naa yoo bẹrẹ, titi di oṣu Karun-un, ọdun 2024.

Gẹgẹ bo ṣe wi, igbesẹ naa wa nibaamu pẹlu ileri ti gomina ṣe lasiko to n ṣepolongo ibo kaakiri pe oun yoo mu igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ lọkun-un-kundun.

O ni gomina ni imọlara ohun ti awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti n la kọja latari owo iranwọ owo epo bẹntiroolu tijọba apapọ yọ lojiji.

Adeleke rọ awọn oṣiṣẹ ijọba lati jẹ ki igbesẹ ijọba naa jẹ koriya fun wọn, ki wọn si tẹpa mọṣẹ ni gbogbo ẹka ti wọn wa.

Leave a Reply