Monisọla Saka
Oluṣọ agba fun ijọ Celestial Church of Christ, to wa lagbegbe Ketu, nipinlẹ Eko, Ọlatọshọ Ọshọffa, ti koro oju si ọkan ninu awọn ẹka ijọ wọn to gbe eto kan ti wọn pe ni ‘Aṣaalẹ Iyin’ (Ankara/Praise Night), kalẹ. Ki i ṣe pe eto ọhun ni Oluṣọ naa n binu si bi ko ṣe awọn elere ti wọn pe fun eto ti wọn fẹẹ ṣe ọhun.
Gbajugbaja olorin Fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi, tawọn eeyan mọ si Pasuma, ati ọkunrin olorin taka-sufee to gba igboro kan nisinyii, Habeeb Okikiọla Ọmọlalọmi, ti gbogbo eeyan n pe ni Portable Zaazu Zeh, ni wọn pe gẹgẹ bii olorin si ile ijọsin ọhun.
Gbara ti iwe ikede eto ti aworan Pasuma ati Portable wa ninu ẹ yii ti gba ori ẹrọ ayelujara kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lawọn eeyan ti n sọrọ buruku si ijọ naa ati awọn to wa nidii eto ọhun, nitori iru awọn olorin ti wọn pe sibẹ. Wọn ni kin ni awọn olorin Fiji ati Portable n ṣe nibi eto to jẹ mọ ṣọọṣi, nigba ti ki i ṣe pe wọn ko ri awọn olorin Kirisitẹni nilẹ to le waa kọrin fun wọn.
Lọjọ Wẹsidee ọhun kan naa, ni Ọshọffa, ti i ṣe Oluṣọ ati olori ṣọọṣi Cele ti gba oju opo ibanidọrẹẹ Facebook rẹ lọ. Nibẹ lo ti ṣalaye pe oun ti ba pasitọ ẹka ijọ naa sọrọ, ati pe awọn olorin to wa ninu iwe ipe ọhun kọ ni yoo kọrin nibẹ mọ.
“Ẹyin ọmọ olu ijọ mimọ Celestial, mo ti ba Oluṣọ to n ṣakoso ijọ yẹn sọrọ. O si ti ṣeleri fun mi lati ṣe atunṣe. O ti ni awọn elere ti wọn fọnrere wọn tẹlẹ yẹn ko ni i wa fun isin alẹ ọjọ yẹn mọ”.
O ni posita ti wọn n lẹ kiri yẹn jẹ nnkan idojuti ti ko bojumu nitootọ lati pe awọn ti wọn n kọ iru orin yii siru ajọdun bẹẹ. Bẹẹ lo ṣadura pe ki Ọlọrun tubọ bukun fun ijọ Celestial.
Ṣaaju asiko yii ni Portable olorin, ọkan ninu awọn ti wọn fiwe pe lati waa ṣere nibẹ ti gbe ọrọ naa sori ayelujara, to si n pe gbogbo awọn eeyan pe ki wọn waa pade oun ninu ijọ Sẹlẹ naa, nibi ti oun ti maa forin aladun da wọn laraya.
Ṣugbọn pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe bu ẹnu atẹ lu eto ti wọn pe ni ‘Ankara Night/Praise yii, ti awọn agba ijọ naa si ti koro oju si awọn olorin ti wọn fẹẹ pe, ko jọ pe Portable to ti n fọnrere eto naa yoo le lọ sibẹ mọ.