Ibrahim yii ma laya o, mọṣalaṣi lo ti lọọ ji mọto onimọto gbe

Adewale Adeoye

Ẹru tabi ipaya kankan ko ba ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Ibrahim Mohammed, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, pẹlu bo ṣe lọọ ji mọto ayọkẹlẹ Toyota Vibe kan gbe niwaju mọṣalaṣi Jimoh nla kan niluu Kaduna.

ALAROYE gbọ pe ọmọ bibi agbegbe Unguwan Gyadi-Gyadi, nipinlẹ Kano, ni Ibrahim yii, ṣugbọn agbegbe Gwarimpa, niluu Abuja lo n gbe. Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, lo lọ si mọṣalaṣi nla Jimoh kan to wa nijọba ibilẹ Zaria, nipinlẹ Kaduna, to lọọ ji ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Vibe kan ti nọmba rẹ jẹ MRR 227 AA ti ẹni to ni in paaki siwaju ibẹ to fi lọọ kirun ninu mọṣalaṣi.

Nigba to maa fi jade sita lẹyin to pari irun to n ki ni ko ba mọto rẹ nibi to gbe e si mọ, loju-ẹsẹ lo si ti sare lọọ fọrọ  naa to awọn ọlọpaa agbegbe ọhun leti.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, S.P Ahmed Wakili to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, sọ pe, ‘ṣe la gba ipe pe wọn ti ji mọto ayọkẹlẹ Toyota Vvibe kan to jẹ alawọ pupa gbe, awọn ọlọpaa ko si fi taratara sun lori ọrọ ọhun, ṣe ni wọn n wo gbogbo ọkọ to jọ iru mọto ayọkẹlẹ ti wọn kede rẹ pe wọn ji gbe yii lawọn oju ọna kaakiri. Ko si pẹ rara tawọn agbofinro kan to wa loju titi ti wọn n ṣiṣe lọwọ fi da Ibrahim duro pẹlu iru ọkọ ta a n wa yii loju ọna marosẹ Bauchi si ipinlẹ Plateau, gbogbo ọrọ ti wọn  n bi i nipa mọto naa ni ko le fesi gidi si, ni wọn ba fọwọ ofin mu un ju sahaamọ wọn. Nigba ti wọn ye inu mọto ọhun wo, wọn ba gbogbo iwe rẹ nibẹ.

‘‘Iwadii ta a ṣe fi han pe ole ni Ibrahim yii, o si ti pẹ to ti n ji mọto gbe, lẹyin to ba ji i gbe tan ni yoo lọọ ta a fawọn onibaara rẹ lowo pọọku lọna to jin sibi to ti ji i gbe. O ti jẹwọ fun wa pe loootọ loun ji mọto ayọkẹlẹ ọhun niwaju mọṣalaṣi nla Jimoh kan nipinlẹ Kaduna, lasiko ti ẹni to ni mọto ọhun n kirun lọwọ.

Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ Bauchi, C.P Auwal Mohammed, ti sọ pe kawọn ọmọọṣẹ rẹ tete fa ọdaran ọhun le awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, nibi to ti ji mọto ọhun gbe lọwọ, ki won le ba a ṣẹjọ lori iwa ọdaran to hu yii.

Leave a Reply