Ọkọ mi n lepa ẹmi mi pẹlu ada, mi o ṣe mọ-Kẹmi

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Abilekọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, lawọn tọkọ-taya meji kan, Abilekọ Kẹmi Ọpẹbiyi ati Ọgbẹni Isaac Ọpẹbiyi, wọ ara wọn lọ. Abilekọ Kẹmi lo gbẹjọ ọkọ rẹ lọ sile-ẹjọ naa pe ki adajọ ile-ẹjọ ọhun ba oun tu igbeyawo ọlọdun gbọọrọ to wa laarin awọn mejeji ka, ki kaluku awọn le maa lọ layọ ati alaafia bayii.

Ninu ọrọ rẹ nile-ẹjọ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘Oluwa mi, inu mi maa dun gidi bẹ ẹ ba le tu igbeyawo ọlọdun gbọọrọ to wa laarin emi pẹlu ọkọ mi yii ka, mi o figba kankan gbadun igbepọ emi pẹlu rẹ latigba ta a ti fẹra wa. Loootọ, Ọlọrun fi awọn ọmọ to daa saarin igbeyawo wa yii, ṣugbọn gbogbo ẹnu ni mo fí le sọ ọ pe ẹtan ni ọkọ mi fi fẹ mi sile rẹ.

‘‘Ko soootọ kankan lẹnu rẹ, ipinlẹ Ondo, lọkọ mi ti n ṣiṣẹ nigba ti emi atawọn ọmọ mi n gbe niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyo, ko sigba to maa de siluu Ibadan ti ki i ba mi fa wahala, ko figba kankan gba mi gbọ, ṣe la a sọ pe ki n maa fi bibeli bura pe ni gbogbo asiko toun ko fi si nile, ọkunrin kankan ko gori mi rara. Gbogbo bi mo ba si ti n sọ pe ko s’ohun to jọ bẹẹ ni wahala rẹ maa n pọ si i.

‘‘Kẹ ẹ si maa wo o, iya to bi mi lọmọ gan-an lo ṣeto ba a ṣe ti fẹra wa o, awọn lo ṣe alarina laarin awa mejeeji, ko too di pe a fẹra wa sile gẹgẹ bii tọkọ-taya, mo ni i lọkan lati lọ sileewe giga, ṣugbọn nigba to fun mi loyun tan, gbogbo erongba ọhun bomi lọ. Ko ṣegbeyawo kankan fun mi, bẹẹ ni ko sanwo-ori fawọn obi mi rara, mo kan n bimọ fun un ni nigba gbogbo.

‘‘O ti bimọ sita lai jẹ ki n mọ rara lẹyin ta a fẹra wa tan lọmọ naa ṣẹṣẹ n waa sile. Nigba miiran, ọmọ naa aa sun d’ọjọ keji lọdọ wa. Ọpọ igba lo jẹ pe awọn obi mi lo maa n sanwo igbẹbi mi lọdọ iya agbẹbi, ko lohun meji to mọ ọn ṣe ju pe ko fun mi loyun lọ. Ki i ṣetọju inu ile atawọn ọmọ ti mo bi fun un rara, ohun gan-an to ṣe gbẹyin to fi mu mi pe ki n pa ọkan mi pọ lati kọ ọ silẹ bayii ni pe, ṣe lo fẹsun kan mi pe mo fun ale mi lẹgbẹrun lọna ọgọta Naira lara owo oun, o si n leri bayii pe ṣe loun maa fada ṣa mi pa patapata bi mi o ba f’oun lowo oun pada, bẹẹ ko s’ohun to jọ bẹẹ rara, mi o ni ale kankan nita debii pe ma a fun ọkunrin lowo.

‘‘Ohun ti mo n fẹ gan-an ni pe ki adajọ ile-ẹjọ yii paṣẹ pe ki n maa ṣetọju awọn ọmọ to wa laarin awa mejeeji, ṣugbọn ki wọn sọ fun un pe ko maa waa ṣojuṣe rẹ fawọn ọmọ naa nigba gbogbo, bakan naa ni ki wọn ba mi kilo f’ọkọ mi pe ko yee lepa ẹmi mi kaakiri gẹgẹ bo ti ṣe n sọ bayii’’.

Nigba ti ko si olujẹjọ nile-ẹjọ, adajọ sun igbẹjọ siwaju dọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024. Bakan naa lo kan an nipa fawọn akọwe kọọtu pe ki won ri i daju pe wọn lọọ fun olujẹjọ niwee ipẹjọ tuntun, ko le yọju si kootu lọjọ ti igbẹjọ rẹ maa waye.

Leave a Reply