Faith Adebọla
Ọtafa-soke yido-bori, b’ọba aye ko ri ọ, tọrun n wo ọ. Ọrọ ikilọ yii lo wọ bọwọ awọn agbofinro ṣe tẹ awọn afurasi ọdaran meji kan, Elvis Gordon, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ati Baridapdo Igia, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ti wọn n ṣe adari ẹgbẹ okunkun meji kan, Iceland ati Demgbam, pẹlu awọn isọmọgbe wọn gbogbo, ti wọn n paayan, ti wọn si n dalu ru nijọba ibilẹ Khana, nipinlẹ Rivers.
Wọn lawọn mejeeji yii ti jẹwọ pe ni tododo, awọn lawọn ṣeku pa ọkunrin kan ti wọn n pe ni Praise Daakian, lẹyin tawọn ji i gbe, tawọn si gba ẹgbẹrun lọna igba naira owo itusilẹ lọwọ iyawo rẹ, amọ dipo ki wọn tu u silẹ, niṣe ni wọn gbẹn koto, ti wọn si ri ọkunrin naa mọlẹ laaye, wọn pa a ku fin-in fin-in, bẹẹ ọkunrin ti wọn pa ọhun ni alaga igbimọ to n ri si idagbasoke adugbo Kereken-Boue.
Kọmiṣanna ọlọpaa tuntun nipinlẹ Rivers, CP Ọlatunji Disu lo ṣafihan awọn afurasi ọdaran yii lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ Kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii, gẹgẹ bii apakan aṣeyọri tawọn agbofinro n ṣe nipinlẹ naa.
Disu ni awọn afurasi yii ti jẹwọ pe awọn lawọn wa nidii bi omi alaafia agbegbe Kereken-Boue, nijọba ibilẹ Khana, ṣe n figba gbogbo daru lati bii ọdun mẹta sẹyin.
Yatọ si ti alaga ti wọn fiwa ọdaju ran lajo aremabọ yii, wọn lawọn afurasi ọdaran mejeeji yii tun jẹwọ pe laarin ọdun 2021 si 2023 ta a wa yii, o ti to eeyan mẹsan-an tawọn ti pa bii ẹni pa eṣinṣin, eyi si wa lara ohun tawọn olugbe agbegbe yii fi n ko kuro, to si jẹ inu ibẹrubojo lawọn kọọkan to ṣẹku n gbe.
Kọmiṣanna Disu ni awọn tọwọ ba yii ni wọn ṣeranwọ fawọn ọlọpaa ti wọn fi ri ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ imulẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ laabi wọn mu.
O lawọn ṣi n ba iwadii to lọọrin niṣo lori awọn afurasi tọwọ ba yii, lati le tuṣu ọrọ wọn desalẹ ikoko, ki wọn too taari wọn siwaju adajọ, nibi ti wọn yoo ti ri pipọn oju ofin.
Ninu awọn afurasi ọdaran ti wọn ṣafihan wọn lọjọ Mọnde ọhun tun ni ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Essien Emmanuel wa, wọn lẹẹmẹta ọtọọtọ loun ti gbadajọ ẹwọn lọwọ adajọ lori ẹsun idigunjale atawọn iwa aidaa mi-in, amọ ọrọ ko dun gbọrọ, ba a fẹ ẹ laaarọ yoo si ruwe lalẹ, lọrọ tiẹ. Wọn ni bo ṣe n jade lẹwọn lo n pada sidii iwa ọdaran, bẹẹ naa ni wọn si n mu un nigbẹyin.
Ni bayii ṣa, wọn tun ti mu un, o si ti n ṣẹju pako lakolo ọlọpaa, nibi ti iwadii rẹ ti n tẹsiwaju.