Awọn agbaagba Yoruba fẹẹ ṣeranti Ogun Kiriji n’Ibadan

Aderounmu Kazeem

Ilu Ibadan yoo gba alejo nla ni Ọjoruu, Wẹside, ọsẹ yii nigba ti awọn agbaagba Yoruba ati awọn ẹgbẹ loriṣiriiṣi ba kora jọ pẹlu awọn ọba alaye lati sami ayẹyẹ ọdun kẹrinlelaadoje (134) ti ẹya Yoruba parapọ lati jẹ ọkanṣoṣo lẹyin Ogun Kiriji.

Ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan-an ọdun 1886 ni ogun Kiriji wa sopin lẹyin ti gbogbo ilẹ Yoruba pata ti fi ọdun mẹrindinlogun doju ija kọra wọn. Ogun Kiriji yii naa ni wọn tun n pe ni ogun Ekiti parapọ. Lasiko ogun naa, iha meji lawọn ọmọ ogun ọhun pin si, awọn kan fara mọ awọn ọmọ ogun Ekiti, nigba ti iha keji fara mọ awọn ọmọ ogun Ibadan, bẹẹ logun ọhun gbona janjan.

Alakooso ipade naa, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ẹni to tun jẹ Aarẹ gbogbo-gboo fun ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba lagbaye sọ pe o ṣe pataki ki ipade ọhun waye lati fi sami ayajọ ọjọ naa, ati pe lati isiniyi lọ, gbogbo ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan-an ọdun ni awọn ọmọ Yoruba yoo maa kora jọ lati sami ọjọ iṣọkan wọn.

O ni, lọjọ naa, awọn Ọba alaye, awọn mọlẹbi awọn jagunjagun ti orukọ wọn wa ninu itan ni wọn yoo peju-pesẹ, bẹẹ gẹgẹ lawọn ọmọ Yoruba yoo lọ si awọn aaye ti ogun naa ti gbona gidi bii ilu Igbajọ, Imẹsi Ile ati ni Oke Imẹsi nipinlẹ Ekiti lati lọọ ṣe ifilọlẹ ami ti yoo duro fun iṣọkan ati alaafia ilẹ Yoruba.

Lara awọn aṣaaju ỌmỌ Oduduwa to maa wa nibẹ ni Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ, Ojiṣẹ Ọlọrun Ayọ Ladigbolu ti ẹgbẹ Yoruba Unity Forum, Adajọ-agba Ademọla Bakare, ti ẹgbẹ igbimọ agba Yoruba ati Ọjọgbọn Adetoun Ogunṣẹyẹ, ẹni ti i ṣe aṣaaju awọn obinrin nilẹ Yoruba pẹlu awọn agbaagba mi-in atawọn ọba alaye.

Ọjọgbọn Banji Akintoye sọ pe pataki ipade ọlọjọ meji yii ni lati fi wa idagbasoke ati iṣọkan si ilẹ Yoruba. Bakan naa lo rọ gbogbo ọmọ Yoruba pata lati peju sibi ipade ọhun, ki wọn si kun eto naa lọwọ fun aṣeyọri gidi.

 

Leave a Reply