Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, ti fọwọ ofin mu awọn ọlọpaa mẹrin kan ti wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe ji oṣiṣẹ otẹẹli igbalode kan to wa niluu naa gbe sa lọ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aṣaale ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, ni awọn ọlọpaa ọhun da Ọgbẹni Darlinton to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ otẹẹli igbalode kan to wa lagbegbe naa duro lakooko to n dari bọ lati ẹnu iṣẹ rẹ. Wọn yẹ ara rẹ wo finni-finni boya o lẹbọ lẹru, ṣugbọn wọn ko rohun kankan to lodi sofin rara lara rẹ. Lẹyin naa ni wọn mu un lọ sagbegbe Choba, nijọba ibilẹ Obio-Akpor, nipinlẹ Rivers, wọn yẹ gbogbo inu foonu oṣiṣẹ naa wo boya wọn aa ri ohun aburu nibẹ, ṣugbọn pabo ni gbogbo rẹ ja si fun wọn. Nigba ti wọn ri i pe oṣiṣẹ ileeṣẹ otẹẹli igbalode nla kan to wa laarin ilu naa ni onitọhun ni wọn ba kuku ji i gbe sa lọ, ti wọn si n beere fun owo nla lọwọ awọn ẹbi rẹ ko too di pe awọn maa ju u silẹ. Wọn sọ fun un pe ko pe awọn ẹbi rẹ to lowo lọwọ lati gbe owo tawọn n beere fun lọwo rẹ wa, bi bẹẹ kọ, awọn lawọn maa pa a danu gẹgẹ bawọn ṣe pa awọn tawọn kọkọ ti ji gbe ti wọn ko r’owo mu silẹ.
Lẹyin ti wọn ṣẹru ba a tan ni wọn ba fi okun de e lọwọ sẹyin, wọn si ju u sẹyin buutu mọto wọn kan, ni wọn ba gbe e lọ sinu igbo nla kan lagbegbe Aluu, nijọba ibilẹ Ikwerre, nipinlẹ Rivers yii, kan naa.
Ṣugbọn ọwọ palaba awọn ọdaran ọhun segi lẹyin tawọn ẹbi ẹni ti wọn ji gbe lọọ fọrọ iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa agbegbe ọhun leti, ti ọga ọlọpaa teṣan ibi ti wọn ti waa fẹjọ sun si ṣe bii baba ẹni ti wọn ji i gbe, to si fẹ ẹ sanwo itusilẹ ẹni ti wọn ji gbe ọhun.
D.P.O ọhun lo rawọ ẹbẹ sawọn ọdaran ọhun pe ki awọn pade lagbegbe kan, ki wọn waa gb’owo ọhun lọwọ oun. Ibi ti wọn jọ fẹnu ko si ni awọn ọdaran ọhun wa ti wọn n duro de ẹni to fẹẹ gbowo wa tawọn ọlọpaa kan to ti wa lagbegbe naa fi gba gbogbo wọn mu pata.
Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa, C.P Ọlatunji Disu, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, pe awọn ọlọpaa mẹrin ọhun ti wa lahaamọ awọn bayii.
O ni, ‘Mo ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, mo si ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa to wa nidii iwadii iṣẹlẹ naa ṣewadii wọn daadaa, ki wọn le fidi ootọ mulẹ laipẹ yii, mo fi n da awọn araalu loju pe, a ko ni i fọwọ bo ọrọ ọhun mọlẹ rara, gbogbo bo ba ṣe n lọ pata lawọn araalu maa gbọ si i’.