Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n koroyin yii jọ lọwọ, ọdọ awon alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Newmarket, niluu Suffolk, lorile-ede UK, ni ọkọ iyawo kan, Ọgbẹni David Olubunmi Abọdunde, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta to lu iyawo rẹ, Oloogbe Taiwo Owoẹyẹ Abọdunde, pa nitori ọrọ ti ko to nnkan wa bayii to n ran wọn lọwọ nipa ohun to ri lọbẹ to fi waaro ọwọ. Bakan naa ni awọn alaṣẹ ilu naa ti lawọn maa too ṣedajọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan afunrasi ọdaran ọhun ki ọsẹ yii too pari.
ALAROYE gbọ pe agbegbe Igogo-Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, ni oloogbe ọhun ti wa, nigba ti ọkọ rẹ wa lati agbegbe Ipoti-Ekiti, nijọba ibilẹ Ijero-Ekiti. Ọdun 2004 lawọn mejeeji pade ara wọn nibi eto pataki kan ni ṣọọṣi 7th Day Adventist, niluu Ọtun-Ekiti, lẹyin ti wọn yan ara wọn lọrẹẹ fun igba diẹ, awọn mejeeji ṣegbeyawo, ti wọn si di tọkọ-taya. Lẹyin ọmọ mẹta ni oloogbe lanfaani lati lọ s’Oke-Okun lati lọọ ṣiṣẹ nọọsi to n ṣe ni Naijiria tẹlẹ lọhun-un. Inu oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni Ọgbẹni Olubunmi too lọọ ba iyawo rẹ nibi to wa niluu oyinbo pẹlu ọmọ mẹta to wa laarin igbeyawo awọn mejeeji.
Ko pẹ rara ti ọkọ oloogbe naa deluu oyinbo ti oniruuru asọ ati ija fi n waye laarin awọn mejeeji, ṣugbọn ti wọn n pari rẹ laarin ara wọn lai jẹ ki ẹnikankan mọ si i.
Lara awọn ẹsun pẹẹpẹẹpẹ ti Olubunmi maa n fi kan iyawo rẹ ni pe irin-ẹsẹ rẹ ko mọ, ati pe ṣe lo kan maa lọ faamia lai nidii. Ju gbogbo rẹ lọ, o ni ki i bọwọ foun ninu ile mọ gẹgẹ bo ṣe ti n ṣe nigba tawọn jọ wa lorile-ede Naijiria tẹlẹ. Gbogbo alaye ti oloogbe naa si n ṣe f’ọkọ rẹ pe igbe aye ilu oyinbo tawọn wa yii yatọ gedegbe si tilẹ Naijiria ni ko wọ Olubunmi leti rara.
Wọn ni ohun ti oloogbe naa n sọ fọkọ rẹ ni pe awọn aa jọ maa pin owo ohun gbogbo san ninu ile ni, ko le baa rọrun fawọn mejeeji.
Ṣugbọn nigba ti Olubunmi ko yee lu iyawo rẹ nitori awọn ohun to n ṣe ninu ile lo mu ki oloogbe naa lọọ fẹjọ ọkọ rẹ sun awọn ọlọpaa agbegbe Suffolk, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii. Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti fọwọ ofin mu ọkọ oloogbe naa lori ẹsun pe o n lu iyawo rẹ ninu ile. Lẹyin ti wọn fọrọ wa Olubunmi lẹnu wo fun aimọye wakati ni wọn ju u silẹ pe ko maa lọ sile, ṣugbọn ti wọn kilọ fun un pe ko gbọdọ tun maa dukooko mọ iyawo rẹ ninu ile tabi nibikibi mọ. Bakan naa ni wọn sọ fun un pe ko gbọdọ dele ti oloogbe naa n gbe to wa lojule 235, Opopona Exning-Newmarket, titi tawọn maa fi waa bawọn mejeeji pari ija to n lọ laarin wọn. Wọn ni bi o ba fẹẹ lohun i ṣe pẹlu iyawo rẹ, ko ri i daju pe ẹni kan wa laarin awọn mejeeji.
Ṣugbọn ṣe lawọn ọlọpaa agbegbe naa gba ipe pajawiri kan lati ọdọ awọn olugbe agbegbe laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, nigba ti wọn dele naa ni wọn ba oku oloogbe nilẹ gbalaja, gbogbo akitiyan wọn lati ji i saye lo ja si pabo, bakan naa ni wọn ba ọkọ oloogbe naa ninu ile, ti wọn si fọwọ ofin mu un ju sahaamọ wọn bayii.
Awọn ọlọpaa agbegbe naa ti lawọn maa tuṣu ọrọ iku oloogbe naa desalẹ ikoko lati mọ ipa buruku ti Olubunmi ko ninu iku iyawo rẹ yii.