Akeredolu gbọdọ gbejọba fun igbakeji rẹ-Ẹgbẹ PDP

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nipinlẹ Ondo, ti ni ọna abayọ kan ṣoṣo si yiyanju ẹsun iwa jibiti oun iwe yiyi ti wọn fi n kan awọn ọmọlẹyin Gomina Rotimi Akeredolu kan lọwọ ko ju gbigbe ijọba fun Igbakeji rẹ, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, lọ.

Alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo, Ọnarebu Fatai Adams, to sọrọ yii lasiko to n ṣepade pẹlu awọn oniroyin kan ni olu ile ẹgbẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kejila yii, ni kikede Ayedatiwa gẹgẹ bii Adele Gomina nikan lo le fopin si bi wọn ṣe lawọn eeyan kan n lo ayederu ibuwọlu Aketi lati tẹ ifẹ inu ara wọn lọrun latigba ti ko ti si nile nitori ara rẹ ti ko ya.

Adams ninu ọrọ rẹ ni amọran awọn si Akeredolu ni pe ko gbe ọrọ Aarẹ Bọla Tinubu ti si ẹgbẹ kan, nitori abajade ipade ti wọn ṣe pẹlu rẹ l’Abuja, ki i ṣohun to le yanju rogbodiyan oṣelu to n lọ lọwọ nipinlẹ Ondo, o ni o yẹ ki ọkunrin ọmọ bibi ilu Ọwọ naa pọn ara rẹ le, ko si funra rẹ gbe ijọba silẹ fun Ayedatiwa gẹgẹ bii alakalẹ ofin Naijiria.

O ni ohun to han kedere ni pe ko si olori kan pato to n dari ijọba ipinlẹ Ondo lọwọlọwọ, leyii to fun awọn ọbayejẹ kan lanfaani ati ja eto iṣakoso gba nitori imọtara tiwọn nikan, ti igbesẹ yii si ti n ṣe akoba nla fun eto inawo, ọrọ-aje ati idagbasoke ipinlẹ naa.

Adams ni bo tilẹ jẹ pe awọn ba Aketi kẹdun gidigidi lori ọrọ aisan to ti da a dubulẹ lati bii oṣu mẹfa sẹyin, ṣugbọn gbogbo ara lawọn fi ta ko bi Akeredolu ṣe ko gbogbo awọn araalu si ẹgbẹ ibusun rẹ lori akete aisan to wa.

O ni awọn n fi asiko yii ran Arakunrin leti ariwo to n pa ati ipa takuntakun to ko lasiko ti Aarẹ Musa Yar’Adua n ṣaisan, amọ ti ko fẹẹ gbe ijọba silẹ fun igbakeji rẹ igba naa, Ọmọwe Goodluck Jonathan.

Adams ni awọn dokita to n tọju Aketi ti kilọ fun un pe ko jinna patapata si ipinlẹ Ondo tabi ile ijọba, nitori ko si okun ati agbara ninu rẹ mọ ti yoo fi maa ba iṣakoso rẹ lọ. Ko waa yẹ ko jẹ iyawo gomina tabi ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ni yoo waa maa fọwọ lalẹ lori ẹni to lẹtọọ lati maa ba eto iṣakoso lọ.

O ni ohun to buru gbaa ni ọkan-o-jọkan awọn iwa ibajẹ to gbilẹ laarin awọn ọmọ igbimọ aṣejọba ati bi ọmọ Aketi, iyẹn Babajide Akeredolu, ṣe n lo awọn ọkọ akọwọọrin to jẹ ti gomina lati lọọ ki awọn ọrẹ rẹ kan nile.

Nipa ti eto isuna, alaga ẹgbẹ alatako ọhun ni ko ṣẹni to le sọ pato ipo ti eto isuna ipinlẹ Ondo wa lati bii ọdun meje ti Akeredolu ti wa lori aleefa, eyi ti ko ri bẹẹ latẹyinwa, nitori oṣooṣu nijọba Agagu ati Mimiko maa n jabọ ibi ti wọn ba eto ísuna de lasiko ti wọn wa lori aleefa.

O ni lara apẹẹrẹ owo ilu ti wọn ṣe bo ti wu wọn ni ti Biliọnu meje Naira, owo palietiifu tawọn ọmọ ẹyin Aketi ṣe basubasu, nitori ọpọ awọn araalu ni wọn n pariwo pe awọn ko ri palietiifu gba bo ti wu ko kere mọ.

Adams tun fi aidunnu wọn han fun bi ẹgbẹ APC ṣe kuna lati gbọran si aṣẹ tile-ẹjọ pa lori awọn adele alaga ibilẹ mọkanlelaaadọta ti wọn ṣẹṣẹ yan laipẹ yii.

O ni Ọjọruu, Wẹsidee ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 lawọn aṣofin ṣayẹwo awuruju kan fawọn adele alaga ọhun atawọn igbekeji wọn, lodi si abala keje ati ikẹjọ ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo, ti ọdun 2006, eyi to pọn ọn ní dandan pe ṣe ni wọn gbọdọ dibo yan awọn alaga ijọba ibilẹ.

O ni ilana ti ẹgbẹ oṣelu PDP tẹle ree ti wọn fi gba ile-ẹjọ lọ lati pẹjọ ta ko igbesẹ ọhun, ti adajọ si paṣẹ fun  wọn lati da igbesẹ naa duro na, ti awọn si wa gbogbo ọna ti iwe aṣẹ kootu fi tẹ awọn tọrọ kan lọwọ.

Adams ni kayeefi lo jẹ fawọn pe akọwe ijọba ipinlẹ Ondo, Abilekọ Ọladunni Odu, pada bura wọṣẹ fawọn Adele alaga naa ni nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla.

O ni awọn ti n ṣeto, ati pe awọn aṣoju ijọba naa lẹjọ lati jẹ, ki wọn le jiya to tọ labẹ ofin fun iwa ṣiṣe afojudi si aṣẹ ti ile-ẹjọ pa.

Ni ipari ọrọ rẹ, alaga ẹgbẹ PDP yii ni ajalu buruku ni ẹgbẹ APC jẹ fawọn eeyan Naijiria ati ti ipinlẹ Ondo, nitori inira ti ko ṣee fẹnu sọ tawọn araalu n foju wina rẹ labẹ iṣakoso wọn.

Adams ni ko si ootọ ninu ọrọ ti alaga ẹgbẹ APC ipinlẹ Ondo, Ade Adetimẹhin, sọ laipẹ yii pe awọn ọmọ igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ PDP meje fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ wọn, O ni ẹnu lasan lawọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ni bii ti atakara, amọ ti ọpọlọ eto iṣakoso rere ko si lagbari wọn.

Nigba to n fun Adams lesi ọrọ rẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila yii, alaga ẹgbẹ All Progressive Congress nipinlẹ Ondo, Ade Adetimẹhin, ni ọrọ ko dun lẹnu Fatai Adams, lori gbogbo awọn ẹsun to fi kan oun ati ẹgbẹ oṣelu APC, nitori awọn ẹsun ọhun ko lẹsẹ nilẹ rara.

Adetimẹhin ni ki Adams tubọ lọọ wadii daadaa lori ọrọ ibura wọṣẹ ti wọn ṣe fawọn Adele alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan. O ni ile-igbimọ aṣofin ni wọn ti ṣe ibura ọhun loootọ, ṣugbọn oun ko si nibẹ lasiko ti wọn n ṣe e.

O ni gbogbo ẹnu loun fi n sọ ọ pe ọpọ awọn alagbara ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti ko si sẹni to ti i pada ninu wọn titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

O waa pe alaga ẹgbẹ PDP nija pe ko darukọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ti wọn ti wa lọdọ awọn, amọ ti wọn ti pada sinu ẹgbẹ PDP ni bonkẹlẹ gẹgẹ bo ṣe sọ.

O ni ko si wahala ninu ẹgbẹ APC ti ipinlẹ Ondo, gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun lo ni awọn wa ni iṣọkan labẹ iṣakoso Gomina Rotimi Akeredolu.

 

 

Leave a Reply