Baba Adeboye sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Adewale Adeoye

Adewale Adeoye

Pasito agba tijọ Onirapada nni, ‘The Redeemed Christian Church Of God’ RCCH, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye, ti sọ pe bi gbigba soke awọn ayanfẹ ko ba tete waye gẹgẹ bii ọkan oun ṣe n pongbẹ rẹ bayii, o maa wu oun lati lati ku lẹyin isin lọjọ isinmi ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde, lẹyin toun ba ti jiyan ati ọbẹ aladidun toun fẹran si i ju lọ tan.

Adeboye sọrọ yii ninu iwaasu rẹ lasiko ipagọ ọlọdọọdun ijọ Ridiimu, eyi ti wọn ṣẹṣẹ pari nilẹ ipagọ wọn to wa nipinlẹ Ogun lọsẹ to kọja yii.

Gbajugbaja Iranṣẹ Ọlọrun tawọn eeyan fẹran ati maa pe ni Dadi G.O, ọhun ni ti Jesu ko ba ti i de gẹgẹ bii ireti awọn Kirisitiẹni, ko wu oun rara ki oun rare tabi ṣe aisan kankan ki oun too ku.

O ni ọrọ yii le maa ya awọn eeyan kan lẹnu, ki wọn si maa beere lọwọ ara wọn pe bawo lẹnikan ṣe le ku lai kọkọ ṣe aisan ṣaaju?

O ni ki i ṣe dandan keeyan ṣaisan ki oluwarẹ too lọ sọrun nitori iriri ti oun ti ni lati ọdọ Ọnku oun kan to ṣalaisi.

O ni ọkunrin naa kọkọ lọ si ṣọọsi lọjọ isinmi, to si jo daadaa niwaju Ọlọrun, lẹyin to pada dele, iyawo rẹ kọkọ wa ipanu kekere kan fun un, eyi to fi panu.

Lẹyin eyi lo ni iyawo rẹ gbe isu kana lati fi gunyan fun un jẹ, ṣugbọn ko duro jẹ iyan ọhun to fi jẹ ipe Ọlọrun lai ṣe aisan rara.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘‘Ẹgbọn mi ti mo n sọ nipa rẹ yii n jo nile rẹ ni lẹyin to de lati ṣọọṣi to lọ lọjọ naa, ṣe ni inu rẹ n dun gidi, ti ọkan rẹ si kun fun ayọ lọjo ọhun, to si ku laijẹ pe, o dubulẹ aisan kankan.

‘’Inu ile igbọnsẹ rẹ niku ka a mọ lọjọ naa, iyawo rẹ paapaa ko mọ rara pe ọkọ oun ti ku, o ti ba a gun iyan to fẹ jẹ ẹ tan lọjọ naa, lo ba lọọ kanlẹkun le e lori lati sọ fun un pe ounje rẹ ti delẹ, ṣugbọn si iyalẹnu rẹ, oku ọkọ rẹ lo ba ninu ile igbọnsẹ ọhun, ẹgbọn mi ti lọọ ba Oluwa rẹ, ko ṣaisan rara, ko jẹ irora, bẹẹ ni ori ko fọ ọ lataarọ di alẹ ko too ku.

‘‘Mo mọ pe awọn kan aa maa bi ara wọn leere pe beeyan ko ba ṣaisan bawo leeyan ṣe le ku, bawo leeyan ṣe maa ku bẹẹ yẹn ta a si ri ọrun rere wọ, mo n sọ fun yin pe ko digba teeyan ba ṣaisan ko too lọọ sọrun rere.

Bi Olọrun ba fa bibọ rẹ sẹyin, ma a lọọ sinmi lookan aya Oluwa mi lọjọ Sandee, lẹyin isin ọjọ naa, ma a si ti jiyan ati ọbẹ aladidun ti mo fẹran si i.’

 

Baba Adeboye ni iru iku yii loun naa n bẹbẹ fun lọdọ Ọlọrun.

Leave a Reply