Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajo Balogun tile-ẹjọ Majisireeti kan to wa niluu Yaba, nipinlẹ Eko, ni wọn foju Ọgbẹni Tajudeen Azeez, ẹni ogun ọdun, to fipa ba ọmọ-ọdun mẹfa lo pọ, tiyẹn si ku mọ ọn labẹ ba.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lagbegbe Ipaja-Ayọbọ, ipinlẹ Eko, lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.
Ṣe ni Azeez fi bisikiiti kan tawọn ọmọde nifẹẹ si daadaa tan ọmọ ọhun wọnu ile akọku kan to wa laduugbo Moricas, ni Ayọbọ, to si fipa ba a sun to ẹẹmẹrin, lakooko to n fipa ba ọmọ ọhun sun lọwọ ni ọmọ kekere ọhun dakẹ mọ ọn labẹ, nitori ti ko tete ju ọmọ ọhun silẹ pẹlu iṣekuse to n ṣe pẹlu rẹ. Gbara ti Azeez ri i pe ọmọ naa ko mi mọ labẹ rẹ lo ti sa lọ patapata, to si ju ọmọ naa silẹ nihooho, nibi to ti n ba a sun.
Lẹyin ti mama ọmọ ọhun de lati ori ikiri ọja to lọ lo bẹrẹ si i wa ọmọ rẹ kaakiri. Nigba to wa a titi ti ko ri i lo ba figbe bọnu, awọn kọọkan ti wọn ri Azeez pẹlu ọmọ naa gbẹyin ni wọn sọ fun mama rẹ pe Azeez lo ba ọmọ ọhun ṣere gbẹyin. Nigba tawọn ọlọpaa Ayọbọ fọwọ ofin gba a mu daadaa lo jẹwọ fun wọn pe, loootọ loun fi bisikiiti tan ọmọ ọhun wọnu ile akọku kan to wa lagbegbe naa, ti oun si fipa ba a lo pọ, ati pe ẹnu ibalopọ ọhun lọmọ ọdun mẹfa naa ku mọ oun labẹ si.
Ọlọpaa olupẹjọ, Abilekọ Chekwube Okeh, to foju Azeez bale-ẹjọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, sọ ni pe, ‘‘Oluwa mi, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii, ni olujẹjọ lọ sile mama ọmọ ọdun mẹfa ọhun, o fi bisikiiti tan an wọnu ile akọku kan to wa lagbegbe naa, o fipa ba a sun. Lakooko to n ba a sun lọwọ lo fọwọ bo o lẹnu, ṣugbọn nigba ti ọmọ naa ko le mi daadaa mọ lo ku mọ ọn labẹ, ti ọmọkunrin yii si sa lọ patapata. Kẹ ẹ si maa wo o, inu oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, ni olujẹjọ ṣẹṣẹ gba itusilẹ lọgba ẹwọn to wa. Gbogbo awọn ẹsun ta a fi kan an pata ni ofin ilu Eko ko faaye gba rara’’.
Nigba to n fesi si ẹsun naa, olujẹjọ ni ki adajọ ṣiju aanu wo oun, nitori pe ki i ṣe ifẹ inu oun lati pa ọmọ ọhun.
Adajọ ni ki wọn maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn Kirikiri, niluu Eko, to ti n bọ tẹlẹ. Bakan naa lo ni ki wọn gbe faili rẹ lọ sọdọ ajọ to n gba adajọ lamọran, ‘Department Of Public Prosecution’ (DPP) niluu Eko, fun amọran nipa ẹjọ rẹ.
O sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024.