Adewale Adeoye
Ẹsẹ ko gbero nile awọn baba iyawo tuntun, Omidan Joy Onojaife, ti Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ gbogbo Yoruba, Iba Gani Adam’s, ṣẹṣẹ fẹ niluu Eko lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii, nibi to ti lọọ tọrọ rẹ. Arọ ti ko le rin daadaa paapaa ni ki wọn gbe oun lọọ woran.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko fọrọ ayẹyẹ igbeyawo akọni ọhun ṣe kaye-gbọ rara, sibẹ, ọpọ to gbọ nipa ayẹyẹ ọhun ni inu wọn dun si i gidi, nitori ti wọn ti n reti pe ọjọ wo gan-an ni Iba Gani Adam’s maa fẹyawo keji gẹgẹ bo ṣe jẹ pe awọn ti wọn ti jẹ Aarẹ Ọnakakanfo ṣaaju rẹ fẹ ju iyawo kan lọ nigba aye wọn. yii lo fi han gbangba pe akinkanju ati akin ni Aare Ọnakakanfo jẹ.
Ọkan lara ile baba iyawo to wa niluu Eko ni eto idana ati fifa iyawo le ọkọ lọwọ ti waye, ẹbi, ara ati ojulumọ idile mejeeji lo wa nikalẹ lọjọ naa.
Ori Ade tilu Shasha, nipinlẹ Eko, Ọba Babatunde Ogunronbi, Ariwajoye, lo ṣaaju ikọ awọn ebi ọkọ lọ sibi inawo ọhun, lara awọn eeyan jankan-jankan ati alejo ti wọn tun wa lori ijokoo lọjọ naa ni, Ọjọgbọn Kọlawọle Raheem, Oloye Babaji Tanimọwo, Oloye Dauda Asikolaye, Oloye Yinka Oguntomehin, Oloye Kazeem Hamzat, Ọgbẹni Oluṣeun Ajiboye to ti figba kan jẹ akọwe agba fun gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Iyawo tuntun ti Iba Gani Adam’s ṣẹṣẹ fẹ yii lo jẹ ọmọ ilu Urhobo, nipinlẹ Delta, to si kawe gboye nileewe giga Fasiti ipinlẹ Delta. Bakan naa lo tun jẹ pe o ṣi wa lẹnu ẹkọ miiran lati gboye kun oye rẹ nileewe giga.
O ti figba kan gba ade obinrin to rẹwa ju lọ nipinlẹ Delta lọdun 2012, to si lọọ ṣoju ipinlẹ Delta nibi idije obinrin awẹlẹwa ti wọn maa n ṣe nilẹ wa lọdọọdun lati mu ẹni to maa lọọ ṣoju orile-ede wa nibi idije ti agbaye.