Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gbajugbaja ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ti fa ibinu yọ si Deji tilu Akurẹ, Ọba Aladetoyinbo Aladewusi, lori bi wọn ṣe ti gbọngan ilu ọhun pa, wọn ni ko ni i saaye fun un lati lo o fun ipade ifẹhonu han to n gbero lati ṣe l’Akurẹ mọ, wọn ni ko waa gbowo to san pada.
Ṣoworẹ to jẹ ọmọ bibi ilu Kìrìbó, nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, nipinlẹ Ondo, lo ti kọkọ fi atẹjade kan sita loju opo Fesibuuku rẹ pe oun atawọn eeyan kan fẹẹ ṣe ipade apero ninu gbọngan ilu to wa lagbegbe Ọja Ọba, l’Akurẹ, eyi ti yoo yọri si ifẹhonu han to lagbara ni gbogbo ipinlẹ Ondo, ti Gomina Rotimi Akeredolu ba fi kuna lati kọwe fipo silẹ titi ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila yii.
Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila yii, kan naa ni Ṣoworẹ tun lọ ṣoju opo Fesibuuku rẹ yii kan naa, nibi to kọ ọ si pe awọn ẹṣọ alaabo kan ti n dunkooko mọ Deji, leyii to mu ki Ọba Aladetoyinbo ran awọn ẹmẹwa rẹ kan si oun pe ki oun waa gba owo gbọngan tí oun san pada nirori ipade apero ti oun gbero rẹ ko ni i le waye mọ nibẹ.
Ṣoworẹ ni loju-ẹsẹ loun ti sọ fawọn ẹmẹwa ti Ọba Aladetoyinbo ran si oun pe irọ ni wọn pa, o di dandan ki ipade yii waye, bẹẹ lawọn ko ṣetan lati ṣe e nibomi-in ju inu gbọngan ti awọn ti sanwo rẹ lọ, nitori odo ki i san ko boju wẹyin, o ni ti Deji ba fi kọ jalẹ, ti ko silẹkun gbọngan yii fun awọn, ko yaa maa mura ati gba alejo oun atawọn igbimọ oun ninu aafin rẹ, nitori nibẹ gan-an lawọn yoo ti ṣe ipade ti awọn fẹẹ ṣe ṣaaju ifẹhonu han.
Nigba ta a kan si Ọgbẹni Michael Adeyẹye to jẹ akọwe iroyin fun Deji tilu Akurẹ, alaye to ṣe fun wa ni pe Ṣoworẹ atawọn ikọ rẹ ko jẹ oloootọ rara nigba ti wọn waa ba awọn igbimọ ti Deji ṣeto lati maa bojuto gbọngan ilu yii.
O ni ọtọ lohun ti wọn ni awọn fẹẹ ṣe ki wọn too gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ti wọn san silẹ lọwọ wọn.
Adeyẹyẹ ni lẹyin ti aṣiri tu si awọn igbimọ yii lọwọ pe irọ ati ẹtan ni wọn fi waa gba gbọngan yii silẹ ni wọn pe wọn lati waa gba owo wọn pada.
O ni ko si ẹṣọ alaabo kan to n dunkooko mọ Ọba Aladetoyinbo rara, awọn igbimọ ilu ni wọn mọ-ọn-mọ ṣe ipinnu naa funra wọn.
Ṣugbọn afaimọ ki wahala ma ṣẹlẹ, iyẹn ti Ṣoworẹ ba faake kọri delẹ pe afi dandan ki awọn lo gbọngan ọhun, nitori ọba alaye yii naa ko ni i fẹẹ ri pipọn oju ijọba, eyi ti ko ni i jẹ ko gba wọn laaye.
Tẹ o ba gbagbe, Ṣoworẹ nikan kọ ni ajafẹtọọ ti yoo pariwo pe ki wọn jẹ ki Igbakeji Gomina, Lucky Ayedatiwa bọ sori isakoso gẹgẹ bii adele gomina ipinlẹ Ondo, niwọn igba ti ailera Akeredolu ko jẹ ki o ṣe awọn ohun to yẹ lati ṣe nipinlẹ naa.
Ṣugbọn awọn aṣofin atawọn oloṣelu kan ko gba, funra wọn ni wọn n da ijọba ṣe, ti wọn si n fi orukọ gomina naa hu iwa ikowojẹ loriṣiiriṣii.