Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Eeyan mẹta ti mọto tanka kan run mọlẹ ninu ṣọọbu ti wọn wa ni wọn wa l’ẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun bayii nileewosan ijọba nibi ti wọn ti n gbatọju lọwọ.
Mọto tanka ọhun to jẹ alawọ buluu ni taya rẹ fọ, to si lọọ ya bara wọnu ṣọọbu tawọn onitọhun ti n taja, ati awọn ero inu kẹkẹ Maruwa to wa lẹṣẹ titi, to si ṣe wọn basubasu
Iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye lagbegbe Ogidi, niluu, Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun yii, ni iṣẹlẹ laabi ọhun ṣẹlẹ.
Ọkan lara awọn araadugbo ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye to ni ka ma darukọ oun sọ pe taya tanka yii lo fọ lojiji, to si ya wọ inu ṣọọbu kọntẹna ti Arabinrin Sidikata ati ọmọ rẹ, ẹni ọdun meji, sun si, awọn araadugbo lo si pada yọ wọn jade labẹ tanka ọhun.
O ni, ‘Lati ọna Oko-Olówó, niluu Ilọrin, ni mọto ọhun ti n bọ, ṣugbọn asiko to de ṣọọbu Sidikata yii, o kọkọ run kẹkẹ Maruwa to wa niwaju ṣọọbu ọhun mọlẹ, ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun lara awọn to wa ninu kẹkẹ ọhun fara pa, ti wọn si ti ko awọn mẹtẹẹta to nijamba yii lọ si ileewosan fun itọju to peye.
O tẹsiwaju pe gbara ti iṣẹlẹ naa waye ni awakọ mọto ọhun ti sa lọ.
O ni ileewosan ijọba kan ti wọn pe ni Cottage, lagbegbe naa, ni wọn kọkọ gbe awọn to fara pa lọ ko too di pe wọn dari wọn lọ sileewosan ijọba Jẹnẹra ipinlẹ naa.
Awọn ọlọpaa ti wọ tanka ọhun ati Maruwa lọ si agọ wọn.