Ọwọ Amọtẹkun tẹ Garuba, ogbologboo ajinigbe to n yọ awọn eeyan Ọ̀sẹ́ lẹnu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹṣọ Amọtẹkun ti ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ogbologboo ajinigbe kan ti wọn porukọ rẹ ni Garuba Usman, ẹni ti wọn loun atawọn ẹmẹwa rẹ n yọ awọn eeyan agbegbe ijọba ibilẹ Ọsẹ lẹnu.

Usman atawọn afuarsi ajinigbe bii mẹjọ ni wọn wa lara awọn ọdaran mejilelọgọta ti wọn ṣe afihan wọn ni olu ileeṣẹ Amọtẹkun to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila yii.

Adari ẹsọ ọhun, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ ninu ọrọ rẹ ni ko din leeyan bii mẹsan-an ti Garuba nikan ti ji gbe, to si gba owo nla atawọn nnkan mi-in lọwọ wọn ko too tu wọn silẹ.

O ni awọn ilu ti ọkunrin Fulani ọhun ti n ṣọṣẹ ju lọ ni Àlà, Dádá, Agọ-Oyinbo atawọn agbegbe mi-in nijọba ibilẹ Ọsẹ.

Adelẹyẹ ni asiko kan wa ti Garuba sun awọn eeyan agbegbe to n yọ lẹnu kan ogiri, ti wọn si gbiyanju lati kọju ija si i. Eyi lo ni o mu ki ọkunrin naa binu tan, to si lọọ wa awọn gende marun-un mi-in pẹlu ara rẹ, ti wọn si jọ lọọ dana sun gbogbo ile to wa labule ọhun.

O ni odidi ọjọ mẹrin lawọn fi wa ninu igbo kọwọ too tẹ pupọ ninu awọn afuarsi ọdaran naa.

Oludamọran fun gomina lori eto aabo naa dupẹ lọwọ awọn araalu fun atilẹyin wọn, eyi to ran Amọtẹkun lọwọ lati le ri ọpọ awọn oniṣẹẹbi ti wọn fẹẹ maa da omi alaafia ipinlẹ Ondo ru mu laarin ọsẹ perete.

O tun fi asiko naa kilọ fawọn ọdaran lati tete kẹru wọn kuro nipinlẹ Ondo, nitori ikoko ko ni i gba ẹyin ko tun gba ṣọṣọ lawọn yoo fi ọrọ wọn ṣe

 

Leave a Reply