Adewale Adeoye
Gbajumọ oṣerebirin onitiata ilẹ wa nni, Iyabo Ojo, ti sọ pe ayẹwo ẹjẹ fun Liam, ọmọ Ilerioluwa Alọba ti gbogbo eeyan mọ si Mohbad tawọn kan n jẹ lẹnu pe dandan ni kawọn se lati fidi ootọ mulẹ boya oloogbe lo ni ọmọ ọwọ Wunmi ti i ṣe iyawo ọmọkunrin naa tabi ki i ṣe oun, lo ni ko si lara ẹhonu ati ilakaka awọn lati ja fun oloogbe ọhun bo ṣe ku lojiji rara.
Iyabo Ojo sọrọ ọhun di mimọ lori ẹrọ alatagba rẹ lasiko to n fesi si bawọn kan ṣe n sọrọ kiri pe o yẹ ki wọn ṣayẹwo ẹjẹ f’ọmọ oloogbe naa.
O ni, ‘‘Mi o fẹẹ mọ ẹni gan-an to jẹ baba Liam bayii, ẹni to ba wu ko jẹ, o ye Ọlọrun Ọba, koko ohun gan-an ti emi duro le lori bayii ni lati ja fun oloogbe naa, ko yẹ kawọn to pa a ni rewe-rewe ṣe bẹẹ lọ lai jiya ẹṣẹ ohun ti wọn ṣe yii. Bẹẹ bawọn kan ṣe tun n gbọrọ ayẹwo ẹjẹ ọmọ naa sita bayii, ọgbọn ti wọn n da ni lati ma ṣe jẹ ka tan imọlẹ sọrọ ọhun mọ, wọn fẹẹ ṣi wa lọna. Ọgbọn ti wọn n da ni lati fi dudu pe pupa fun wa, a ko si ni i gba rara, nitori pe ayẹwo ẹjẹ f’ọmọ oloogbe naa ko si lara idi ta a ṣe gbọrọ iku rẹ lori latigba to ti ku. Awọn kan ni wọn n lo ọgbọn ẹwẹ lati ṣi wa lọna lori ọrọ ayẹwo ẹjẹ ọmọ ọhun, ko si eyi to kan wa nibẹ rara, ṣugbọn baba oloogbe gan-an ti bọ sita, to loun n fẹ ki wọn ṣe ayẹwo ẹje fun ọmọọmọ oun nibi meji ọtọọtọ. Gbogbo ohun ti baba naa n ṣe, tabi awọn to n ti i lẹyin n fẹ ni ka ma le ridii ootọ ọrọ ọhun ni, bi wọn ba fẹẹ se ayẹwo ẹjẹ ọhun, ki wọn lọọ ṣe e, ko kan wa rara, ọrọ ẹbi wọn niyẹn, ko s’ohun ta a le ṣe si i rara, ṣugbọn eyi ko sọ pe ka ma ja fun oloogbe yii bi akoko ba to gan-an’’.
Bẹ o ba gbagbe, alagba James Alọba, ẹni ti i ṣe baba oloogbe naa ti bọ sita laimọye igba, to si ti faake kọri pe afi ki oun o ṣe ayẹwo ẹjẹ f’ọmọ oloogbe naa koun too gba pe loootọ, ọmọọmọ oun ni Liam. Koda, o ni ibi meji ọtọọtọ loun ti fẹ ki wọn ṣayẹwo ẹjẹ ọhun, toun si gbọdọ wa lori iduro lasiko naa.