O ma ṣe o, iya at’ọmọ padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ oju omi

Adewale Adeoye

Titi di akoko ta a n koroyin yii jọ lọwọ, awọn alaṣẹ ijọba ilu kan ti wọn n pe ni Gamadio, nijọba ibile Numan, nipinlẹ Adamawa, ṣi n wa awọn ero meji kan ti wọn ba iṣẹlẹ  ọkọ oju omi to waye lagbegbe naa lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun yii lọ.

ALAROYE gbọ pe ero marun-un ni wọn wa ninu ọkọ oju omi ọhun, eyi to gbera ni ebute ilu Gamadio, ṣugbọn ti nnkan yiwọ fun awakọ oju omi yii, nigba ti wọn de aarin agbami, ọkọ naa ri patapata sinu omi, ṣugbọn ori ko awọn ero mẹta kan yọ lọwọ iku ojiji.

Iya ikoko kan to n tọju ọmọ lọwọ wa lara awọn to padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ ọhun bayii.

Alaga ijọba ibilẹ Numan, Ọgbẹni Christopher Sofore, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ  lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu yii, sọ pe ero mẹta ninu awọn tori ko yọ lọwọ iku ojiji ọhun ni awọn ti gbe lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe naa fun itọju to peye, nigba tawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri niluu naa, ‘National Emergency Agency’ NEMA pẹlu iranlọwọ awọn omuwẹ adugbo ọhun n wa awọn to bomi lọ lati ri oku wọn gbe jade.

Lori iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun, igbakeji gomina ipinlẹ naa ba gbogbo awọn ẹbi ti wọn padanu awọn eeyan wọn sinu ijamba ọkọ ọhun kẹdun, to si gbadura fun wọn pe Ọlọrun aa duro ti awọn ẹni ti wọn fi silẹ lọ.

Bakan naa lo rọ awọn ero to n wọ ọkọ oju omi nigba gbogbo pe ki wọn maa wọ aṣọ idaabobo ‘Life Jacket’ .

O ni, ‘O yẹ ki alaga ijọba ibile ọhun pese awọn aṣọ idaabobo fawọn ero ti wọn n wọ ọkọ naa, ko si ri i daju pe o kan an nipa fun wọn pe ki won maa wọ ọ sọrun nigba gbogbo ti wọn ba fẹẹ wọkọ oju omi naa’.

Leave a Reply