Aṣifẹ pata gbaa lọkọ ti mo fẹ yii, adajọ, ẹ tu wa ka- Bọla

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Abilekọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni awọn tọkọ-taya meji kan, Ọgbẹni Morufu Dele, ati Abilekọ Bọla Dele, gbẹjọ ara wọn lọ. Ọkọ iyawo, Ọgbẹni Morufu, lo fẹsun kan iyawo rẹ, ẹbẹ to n bẹ adajọ  ni pe ko tu igbeyawo to wa laarin awọn mejeeji ka, ki kaluku maa lọ layọ ati alaafia. Morufu ti i ṣe olupẹjọ sọ niwaju adajọ pe, ‘Oluwa mi, mi o ṣe mọ o, ọrọ iyawo mi yii ti su mi patapata bayii, ko sifẹẹ kankan mọ laarin awa mejeji, koda, mo ti da gbogbo ẹru rẹ sita ninu ile mi. Orikunkun rẹ ti pọ ju, mi o le fara da a mọ, gbogbo nnkan ti mo ba ka lewọọ fun un pata ni ki i gbọ si mi lẹnu, ṣe lo maa n fọwọ pa ida mi loju’.

Ninu ọrọ rẹ, Abilekọ Bọla toun naa yọju sile-ẹjọ ọhun fun igba akọkọ sọ pe oun paapaa ṣetan lati kọ ọkọ oun silẹ nitori gbogbo iwa rẹ ko yatọ si ti ẹranko inu igbo.

O ni, ‘’Kẹ ẹ si maa wo o, alarena kan lo ṣeto ba a ṣe fẹra wa, onitọhun lo parọ fun mi pe eeyan daadaa ni ki n too gba lati fẹ ẹ, ṣugbọn abamọ nla gbaa ni igbesẹ ti mo gbe yii. Mi o figba kankan gbadun igbeyawo to wa laarin awa mejeeji ri, ojoojumọ ija ni ninu ile, igba kan tiẹ wa to fun mi lọrun, to fẹẹ pa mi, Ọlọrun Ọba lo ko mi yọ lọwọ rẹ. Ọdun Ileya to kọja lo ti ra aṣọ ọdun fawọn ọmọ wa gbẹyin, bẹẹ ba bi i leere owo ounjẹ nile, wahala nla lo maa da. Oun funra rẹ lo kẹru mi jade nile rẹ, mi o si le pada sile naa mọ lae. Ohun ti mo n bẹ adajọ ile-ẹjọ yii fun ni pe ki wọn kan an nipa fun ọkọ mi pe ko jẹ ki n maa ṣetọju awọn ọmọ to wa laarin wa, ṣugbọn ko maa waa ṣojuṣe rẹ fun wọn loṣooṣu nibi ti mo ba n gbe.

Adajọ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2024.

 

Leave a Reply