Adewale Adeoye
Beeyan ba jori ahun, bo ba ri bi ẹran awọn eeyan kan ṣe ja wẹlẹwẹlẹ, to si ri bawọn oṣiṣẹ alaabo ojupopo, ‘Federal Road Safety Corps’ (FRSC) ṣe n fa oku awọn kan yọ labẹ mọto, ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye laaaro kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kejila yii, lagbegbe Kaara, nipinlẹ Ogun, ni nnkan bii aago marun-un owurọ, ko si ki tọhun ma bomi loju gidi ni.
ALAROYE gbọ pe mọto akero Toyota Hiace kan ti kọlọ ara rẹ jẹ awọ eeru ti nọmba rẹ jẹ FKY 898YF, lo lọọ ko sabẹ tirela kan. Ere asapajude wa lara ohun to ṣokunfa ijamba ọhun, ati pe gbogbo awọn ero to fara pa ninu ijamba naa pata lawọn ti ko lọ sileewosan tijọba agbegbe naa, nigba tawọn tun ti ko gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn lọ si mọṣuari kan to wa ni Idẹra, niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun.
Ọga agba ajọ FRSC, Florence Okpe, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ ninu atẹjade to fi sita nipa iṣẹlẹ naa pe, ‘‘O ṣe ni laaanu pe awọn eeyan mẹwaa ni wọn ku sinu ijamba ọkọ kan to waye ni nnkan bii aago marun-un aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Awọn oṣiṣẹ ajọ FRSC agbegbe Mowe, ni wọn lọ sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si ṣohun gbogbo to yẹ nipa ijamba ọhun.
‘‘Lara iwadii ta a ṣe fi han pe ere buruku ti ọkan lara awọn dẹrẹba ọkọ meji ọhun n sa bọ lo ṣokunfa iṣẹle naa. Ọkunrin mejidinlogun lo wa ninu ọkọ ọhun, meje fara pa gidi ninu iṣẹlẹ naa, nigba tawọn mẹwaa miiran ti wọn jẹ ọkunrin ninu ọkọ ọhun ku lasiko ijamba yii. Lasiko ti dẹrẹba ọkọ akero naa n sare lo lọọ kọ lu tirela to fẹẹ ya wọle lagbegbe naa, to si fa ki ọpọ ẹmi ṣofo bayii’’.
Ọga patapata fun ajọ FRSC nipinlẹ Ogun, Kọmadanti C.C Anthony Uga, fajuro gidi si iṣẹlẹ naa, to si rọ gbogbo awọn awakọ ero pata pe ki wọn maa ṣe pẹlepẹlẹ lasiko yii.