O ma ṣe o, eefin jẹnẹratọ pa ololufẹ meji ti wọn n mura igbeyawo sinu ile

Adewale Adeoye

Inu ọfọ nla ni gbogbo awọn olugbe agbegbe Ugborikoko, nijọba ibilẹ Uvwie, nipinlẹ Delta, wa bayii. Ohun to fa a ti ọkan wọn fi gbọgbẹ gidi ko ju bi awọn ololufẹ meji kan ti wọn fẹẹ ṣegbeyawo laipẹ yii, ṣe ku sinu yara ti wọn sun si lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii.

ALAROYE gbọ pe awọn ololufẹ meji ọhun ni wọn lọ sile igbafẹ kan  lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lati lọọ jẹgbadun, bi wọn ṣe n dari bọ wa sile ni ọkọ iyawo ba lọọ sun sile iyawo afẹsọna rẹ nitori ilẹ to ti ṣu. Ṣugbọn nitori pe ooru mu gidi, ti ko sina NEPA, ni wọn ba tan jẹnẹratọ ti wọn n lo. Eefin jẹnẹratọ ọhun lawọn mejeeji fa simu to si ṣeku pa wọn. Ọjọ keji lawọn araadugbo too mọ pe wọn ti ku sinu ile naa, nitori pe wọn ko ri i ki wọn jade sita gẹgẹ bii iṣe wọn nigba gbogbo, paapaa ju lọ nigba ti wọn mọ pe o yẹ ki iyawo ọhun lọ sẹnu iṣẹ oojọ rẹ.

Awọn araadugbo naa lo lọọ fọrọ ọhun to ọlọpaa agbegbe naa leti.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P Bright Edafe, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalayẹ pe oun gbọ si iṣẹlẹ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, to si sọ pe awọn ọlọpaa ti gbe oku awọn ololufẹ ọhun lọ si mọṣuari kan to wa lagbegbe naa.

Leave a Reply