Adewale Adeoye
Ile-ẹjọ Majisireeti kan to ni agbegbe Ajangbadi, nipinlẹ Eko, niwaju Onidaajọ L.K.J Layẹni, ni wọn wọ Pasitọ ijọ Ọlọrun kan, David Eludi, lọ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o parọ gba ẹgbẹrun lọna ọodunrun lọwọ iyaale ile kan, Abilekọ Florence Samuel, to si ṣeleri fun un pe oun fẹẹ ba a ṣiṣẹ iṣẹgun ati irapada, ki gbogbo ogun to n yọ idile rẹ lẹnu le wa sopin patapata. Ṣugbọn kaka ki ogun ti pasitọ ọhun lo maa dopin pari, ṣe ni wahala naa n pọ si i fun iyaale ile naa lojoojumọ.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọndee, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun yii, ni wọn foju Eludi bale-ẹjọ, ti wọn si sọ niwaju adajọ ile-ẹjọ ọhun pe pasitọ huwa laabi ọhun ninu oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Agbefọba, Dọkita Simon Uche, to foju olujẹjọ balẹ-ẹjọ ṣalaye pe agbegbe Jakande, ni Ajangbadi, niluu Ọjọ, nipinlẹ Eko, ti pasitọ ọhun n gbe lo ti huwa gbaju-ẹ ọhun fun iyaale ile yii.
Olupẹjọ ni, ‘‘Oluwa mi, ṣe ni Pasitọ Eludi dọgbọn parọ gbowo nla lọwọ iyaale ile kan. Ohun to loun fẹẹ lo owo ọhun fun ni lati fi ba a ṣiṣẹ iṣẹgun ati iṣẹ aanu lati fi yanju gbogbo oke iṣoro to n koju idile rẹ, ṣugbọn kaka ki ewe agbọn dẹ, ṣe lo n le e si i ni. Ko siyatọ kankan ninu iṣẹ iṣẹgun ati itusilẹ to loun ṣe fun obinrin naa. Pasitọ ọhun atawọn ẹgbẹ ẹ kọọkan ti wọn jọọ parọ gbowo lọwọ iyaale ile naa ti sa lọ bayii, Eludi yii nikan lọwọ ofin tẹ, to si n jẹjọ bayii’’.
Olupẹjọ fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo iwa laabi ti pasitọ ọhun hu pata lo jọ ti gbaju-ẹ, ti ofin ipinlẹ Eko ko si faaye gba a rara.
Ninu ọrọ rẹ, Eludi rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ ọhun, bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun rara.
Adajọ gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira ati oniduuro meji to lorukọ daadaa laarin ilu, to si sun igbẹjọ si ọjọ kejila, oṣu kin-in-ni, ọdun 2024 yii.