Oriire nla: Victor Osimhen gba ade agbabọọlu to daa ju lọ nilẹ Afrika lọdun yii

Adewale Adeoye

Ki i ṣe iroyin mọ rara pe ajọ to n ri sọrọ ere bọọlu afẹsẹgba nilẹ Afrika, ‘Confederation Of Africa Football’ (CAF) ti ṣeto idije lati fun agbabọọlu ọmọ ilẹ Afrika to mọ bọọluu gba ju lọ lọdun yii lami-ẹyẹ, eyi to waye lorile-ede Morocco, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun yii. Iroyin tuntun to wa nibẹ ni pe agbabọọlu ọmọ ilẹ wa to n gba bọọlu jẹun lorile-ede Italy, Victor Osinmhen ni wọn gbe ade ọhun fun. Eyi ja si pe agbabọọlu yii lo peregede ju lọ ni gbogbo Afrika, to si tun fopin si bi awọn agbabọọlu  ilẹ wa ko ṣe ti i gba ade ọhun lati nnkan bii ọdun mẹrinlelogun sẹyin bayii.

Agbabọọlu ilẹ wa kan, Kanu Nwankwo, lo gbade ọhun gbẹyin lọdun 1999, latigba naa, ko sọmọ Naijiria kankan tawọn alaṣẹ ajọ CAF ri i pe wọn kunju oṣunwọn to lati gba ami-ẹyẹ ọhun.

Lara awọn gbajumọ agbabọọlu ti wọn jọ du ade ọhun ni agbabọọlu ọmọ ilẹ Egypt nni, Mohammed Sala, ati agbabọọlu ọmọ ilẹ Morocco, Achraf Hakimi.

Ninu ọrọ rẹ lẹyin ti wọn gbe ami-ẹyẹ ọhun fun un tan ni Victor Osimhen ti dupẹ gidigidi lọwọ gbajumọ agbabọọlu ọmọ orile-ede wa to tun jẹ kooṣi awọn ọjẹ wẹwẹ ilẹ wa, Ọgbẹni Emmanuel Amunike, lori ipa to ko ninu igbesi aye rẹ. O ni kooṣi ọhun wa lara awọn ti Ọlọrun lo lati ran oun lọwọ toun fi di gbajumọ bayii. O ni bi ki i baa ṣe awọn ọgbọn kọọkan toun kọ latara kooṣi ọhun ni, o ṣee ṣe koun ma debi kankan ninu iṣẹ bọọlu toun yan laayo gẹgẹ bii iṣẹ oojọ oun bayii. Bakan naa lo darukọ gbajumọ agbabọọlu orileede Cote d’Ivoire nni, Didier Drogba, gẹgẹ bii agbabọọlu toun n wo awokọṣe rere rẹ lati fi gba bọọlu nigba gbogbo.

Bẹẹ o ba gbagbe, Victor Osimhen yii lo ṣaaju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun lọ, ‘Under 17’, ninu idije ife-ẹyẹ agbeye kan to waye lọdun 2015. Nibẹ nilẹ wa ti gba ami ife-ẹyẹ ọhun, ti wọn si fun Osimhen ni ami-ẹyẹ Golden Boot, gẹgẹ bii agbabọọlu to ṣe daadaa ju lọ ninu idije ọhun.

 

Leave a Reply