Peter Obi ṣabẹwo sawọn ti ṣọja ilẹ wa ju bombu fun, o fun wọn lẹbun owo

Adewale Adeoye

Ondije dupo aarẹ orile-ede yii ninu eto idibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, lẹgbẹ oṣelu ‘Labour-Party’ (LP), Ọgbẹni Peter Obi, ti lọọ ki awọn araalu Tudun-Biri, nipinlẹ Kaduna, nibi tawọn ṣọja ile wa kan ti ṣeesi ju ado oloro fun wọn, ti ọpọ emi si ṣofo laipẹ yii. Miliọnu marun-un Naira lo gbe kalẹ fawọn to fara pa nibi iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun pe ki wọn fi ṣetọju wọn.

Ọsibitu ijọba ipinle ọhun kan to wa lagbegbe Barau-Dikko, nipinlẹ Kaduna, lawọn to fara pa nibi iṣẹlẹ naa wa ti wọn ti n gba itọju lọwọ, ileewosan ọhun si ni Obi ti lọọ ṣabẹwo si wọn lati nawọ ifẹ ati aanu si gbogbo wọn fun ti ajalu to sẹlẹ si wọn yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ lasiko abẹwo ọhun, ‘Mo waa ba gbogbo awọn araalu Tudun-Biri, nijọba ibilẹ Igabi, nipinlẹ Kaduna, kẹdun ajalu buruku to ṣẹlẹ si wọn ni, awọn ọmọ ogun orile-ede wa kan lo ṣeeṣi ju bọmbu lu wọn, wọn ro pe awọn ọdaran lo pe jọ siluu naa ni. Lara awọn ibi ti mo de ni ileewosan awọn akẹkọọ Barau-Dikko, nibi ti awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ naa ti n gba itọju bayii. Adura mi si gbogbo awọn to wa ninu irora ọhun ni pe ki Ọlọrun Ọba Allah tu gbogbo wọn lara pata. Ki Ọlọrun tun rẹ gbogbo awọn idile ti wọn padanu eeyan wọn sinu ijamba naa lẹkun.

O waa dupẹ lọwọ awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Kaduna fun bi wọn ṣe  n ṣetọju awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ naa.

O tun gboriyin fawọn agbofinro gbogbo to wa nilẹ wa fun iṣẹ akọ ti wọn n ṣe nigba gbogbo kiluu le wa ni alaafia.

Lopin ọrọ rẹ, o gba awọn agbofinro ilẹ wa lamọran pe ki wọn maa ṣe jẹẹjẹ, ki wọn si ri i daju pe wọn ṣohun gbogbo to yẹ  ko too di pe wọn koju ija sawọn ọta ilu, ki iru eyi to ṣẹlẹ niluu Barau yii ma baa ṣẹlẹ mọ lọjọ iwaju.

Leave a Reply