Kayeefi kan ree o! Baale ile ṣegbeyawo alarede pẹlu iya to bi iyawo ẹ

Adewale Adeoye

Ai rin jinna lai ri abuke ọkẹrẹ lọrọ da bayii pẹlu bi baale ile kan ṣe wo ṣunṣun, to gbe iya to bi iyawo ẹ niyawo. Nibi tọrọ ọhun si ka a lara de, igbeyawo alarede ni wọn jọ ṣe, ti wọn foruka sira wọn lọwọ. Ni awọn ti ko ri iru ẹ ri ba n pariwo, ti wọn si n beere pe, ‘iru ki leleyii’.

Iyanu n la gbaa lọrọ baale ile ọhun, Ọgbẹni Vashko Sande, ṣi n jẹ fun gbogbo awọn to ri fọto igbeyawo ọhun.

ALAROYE gbọ pe iya iyawo rẹ lo faake kọri pe oun maa fẹ ni tipatipa, o loun nifẹẹ rẹ, oun si fẹ ko fi oun ṣe aya. Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ti iya yii bi ninu wa nile ọkunrin naa to n ṣeyawo fun un lọwọlọwọ.

Gbogbo atotonu tiyawo rẹ Abilekọ Magora, n ṣe fun un pe nnkan eewọ ni ohun ti iya oun fẹẹ ṣe yii ni ko wọ ọ leti rara. Nigba ti apa iyawo ọhun ko si ka a mọ lo ba tun lọọ fọrọ ọkọ rẹ to awọn agbalagba idile ọkọ naa leti boya wọn aa le ba a sọrọ lori ipinnu rẹ yii, ṣugbọn pabo ni gbogbo rẹ ja si.

Wọn ni ni nnkan bii ọdun meje sẹyin bayii ni Ọgbẹni Sande, ti kọ ẹnu ife si iyaayawo rẹ, ti awọn mejeeji si ti n yan ara wọn lale nikọkọ, ko too di pe o dohun ti Ọgbẹni Sande ko le fi bo mọ rara, to fi ni afi dandan ki oun fẹ obinrin naa.

Ija ojoojumọ lo n ba iyawo rẹ ja ninu ile, bẹẹ ni ko ro ti pe iyawo ile oun yii ti bimọ mẹrin foun rara, bo gbe igba ninu ile, yoo ni ko mọ ọn gbe ni, bo gbe awo lọọdẹ, ko mọ ọn gbe mọ ni. Nigba ti iyawo si ri ohun to n ṣẹlẹ lo ba gbiyanju lati lọọ fọrọ ọhun to awọn agba idile ọkọ rẹ leti boya wọn aa pẹtu sọrọ ija naa, ṣugbọn ko niyanju rara. Eyi lo mu ki Abilekọ Magora  gba ile-ẹjọ lọ lọsẹ to kọja yii lati tọwọ ofin bọrọ ọhun.

Alaye to si ṣe ni kootu ọhun ni pe, ‘‘Oluwa mi, ọdun 2008 ni emi pẹlu ọkọ mi ṣegbeyawo, ṣugbọn lati ọdun 2011 niwa rẹ ti yatọ si mi ninu ile, o ti yo ifẹ iya to bi mi lọmọ, awọn mejeeji si ti n palẹmọ bayii lati ṣegbeyawo alarede. Koko ohun ti mo n fẹ  ni pe ko yee lu mi bajẹ nigba gbogbo gẹgẹ bo ti n ṣe bayii. Ere ni mo kọkọ pe e nigba ti mo gbọ pe o n yan iya to bi mi lale. Mo gbiyanju lati jẹ ko fopin sọrọ ifẹ ikọkọ ọhun, ṣugbọn ko gba, mo lọọ fọrọ rẹ to awọn agba idile rẹ leti, wọn ko ri i pari rara’’.

Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Sande loun gba gbogbo ẹsun ti iyawo oun fi kan oun pata, ṣugbọn oun ti pinnu lati fẹyawo keji, ati pe ẹni toun nifẹẹ si lati fi ṣeyawo keji ni iya iyawo oun yii.

Adajọ ile-ẹjọ ọhun paṣẹ pe ko si aburu ninu ki ọkunrin fẹyawo meji sile gẹgẹ bii ipinnu Ọgbẹni Sande yii, ṣugbọn ko jawọ ninu lilu iyawo rẹ nigba gbogbo gẹgẹ bii ẹsun tiyawo rẹ fi kan an yii.

 

Leave a Reply